Ileeṣẹ to n ri si ipolongo Atiku Abubakar fun ti ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ ọrọ kan tawọn kan n gbe e jade pe ọkunrin naa ti n mura lati fẹgbẹ oṣelu naa silẹ lọọ darapọ mọ ẹgbẹ mi-in, wọn ni irọ to jinna sootọ ni.
Ninu atẹjade kan ti Ọgbẹni Ṣẹgun Ṣowumi, to jẹ agbẹnusọ olupolongo fun ileeṣẹ naa gbe jade lọjọ Aiku Sannde, ana an, lo ti sọ pe awọn to n gbe igbekugbe naa jade ko niṣẹ ati pe nnkan ti wọn ko ri i ni wọn n sọ lati yi ọkan awọn alatilẹyin ọkunrin naa pada ni wọn n ṣe e, eyi to sọ pe wọn ti i mu ofo ọjọ keji ọja.
O ni fawọn alaigbagbọ, ko sigba kankan ti Atiku pinnu lati fẹgbẹ naa silẹ bẹẹ si ni ẹsẹ ẹ ko yẹ lati dije fun ipo aarẹto n bọ lọdun 2019. O ni lati nnkan bii oṣu meji sẹyin, lo ni ọkunrin naa ti n rin irinajo kaakiri orilẹ-ede yii lati fi ipinnu ẹ han.
O ni titi di akoko yii lawọn alatilẹyin ẹ ṣi n fi ifẹ wọn han si i pe ko maa niṣo o, awọn wa lẹyin ẹ nibi ibo pamari ti yoo kọkọ waye. Ileeṣẹ olupolongo naa wa ke si awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP pe ki wọn fọkanbalẹ ki wọn maa jẹkawọn onisọkusọ ba ero ọkan wọn je. Idaniloju si wa pe lọdun to n bọ Atiku ni yoo di aarẹ orileede yii.
Capt; Atiku
No comments:
Post a Comment