Ki i ṣe tuntun mọ pe Tunde Lẹmọ, ẹni to ti figba kan jẹ igbakeji ọga agba banki nilẹ wa, ti jade lati dupo fun ipo gomina ninu ibo ọdun 2027, labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹOgun.
Bẹẹ ni igbesẹ si n lọ lọwọ lori bi nnkan yoo ṣe ṣẹnu ire fun oludije ti idaniloju si wa pe gbogbo awọn ọmp Ẹgba ni wọn ti gbaradi lati ṣatilẹyin fun un.
Gẹgẹ bi a ṣẹ mọ lati bi ọjọ meloo kan sẹyin ni ariwo awọn oludije kan ti n lọ laarin igboro fun ibo Gomina ti yoo waye lọdun to n bọ naa.
Lara awọn oludije ọhun ti iroyin wọn ti tan kaaliri ni Ambasedọ Ṣarafa Tunji Iṣọla, Senetọ Ọlamilekan Adeọla, tọpọ mọ si Yayi, Ọnsrebu Gboyega Isiaka, Ọnarebu Abiọdun Akinlade.
Nigba to ya lawọn mii naa tun fi ifẹ wọn han lati dije, lara wọn ni Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, Ọnarebu Hunye, Arabinrin Mọdele Sarafa.
Ṣugbọn lojiji ni ariwo tun gba igboro pe Tunde Lẹmọ naa jade lati dupo, bo tilẹ jẹ pe ahesọ lawọn kan pe e tẹlẹ, ko to di pe ọkunrin naa waa jade fun ara rẹ.
Iwadi fi ye wa pe latilẹ lawọn oloṣelu kan ti n sọ pe ti Tunde Lẹmọ, ba fi le jade iṣoro nla ni yoo jẹ fawọn oludije yooku ti wọn ba jade.
Idi abajọ ni pe ojulowo pọnbele ọmọ Ẹgba ni Tunde Lẹmọ ati pe latigba ti Gomina Dapọ Abiọdun ti n lo ṣaa keji lọ lawọn kan ti n pariwo pe awọn Ẹgba lo kan nitori awọn ko tun le duro fun ọdun mẹjọ miiin.
Wọn ni idi ree ti Sẹnetọ Yayi, to n ṣoju agbegbe Ogun West, ṣe sọ pe ọmọ Ẹgba loun naa nipasẹ iya, nitori ọmọ Kemta ni iya to bi oun.
Ṣugbọn iwadii fi ye wa pe awọn ọmọ Ẹgba gba ki wọn ṣiṣẹ fun Tunde Lẹmọ ju ki wọn ṣiṣẹ fẹni ti wọn ko fi tara tara gba pe ọmọ Ogun ni.
Ẹnikan to ba oniroyin wa sọrọ to ni ka fi orukọ bo oun laṣiiri sọ pe ọrọ ipo Gomina to n bọ yii afaimọ ko ma jẹ pe ọmọ Ẹgba ni tikẹẹti naa yoo ja mọ lọwọ, bẹẹ ni ko n ṣe ẹlomii bi ko ṣe Tunde Lẹmọ, idi niyii tọkan awọn oludije yooku ko ṣe balẹ, nitori o ti fi ijade rẹ ṣẹru ba awọn yooku rẹ

No comments:
Post a Comment