IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 8 March 2026

Awọn Yewa lawọn ko le ta ogun ibi awọn fun Yayi lọdun 2027



Bi ibo Gomina fọdun 2027, ṣe n sunmọ le lorileede yii paapaa julọ nipinlẹ Ogun, oriṣiiriṣii awọn nnkan lo ti n jẹyọ nipa awọn to fẹẹ dije, o si jẹ pe lakooko yii awọn ọmọ Yewa ko fọrọ naa ṣere rara.

Idi abajọ ni pe awọn kan sọ pe bigba tawọn ta ogun ini wọn lọrọ yoo ri tawọn ba fi le gba ki Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla tọpọ mọ si Yayi gẹgẹ bi oludije Gomina lati apa ọdọ wọn.

Ohun tọpọ wọn ka a si ni pe bìgba tawọn to fẹẹ fi eeru gba ibukun lawọn ka si, nitori bi wọn lo ṣe sọ pe ọmọ bibi Ilaro loun, to si tipasẹ bẹẹ jẹ lọ fun ipo sẹnetọ to wa yii.

Wọn ni gbobo awọn iṣẹ akanṣe to n ṣe kaakiri ipinlẹ Ogun lo ye awọn, nitori ko fi le gbe wọn mọra.

Eyi ti wọn sọ pe ko ṣe ida ọgọta iru ẹ nipinlẹ Ogun to ti n kọkọ ṣoju wọn fun ọpọ ọdun sẹyin, to si tumọ si pe ko le ba a gbe awọn ọmọ Ogun mọra.

Loootọ lo jẹ pe lati nnkan bii aadọta sẹyin lawọn apa Ogun West ko ti jẹ gomina ri ṣugbọn tawọn mọ pe o ti to akoko fun wọn lati ni nipasẹ Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka, ẹni to n ṣoju wọn nile igbimọ aṣoji-ṣofin fun ẹkun Imẹkọ Afọn/ Egbado North, niluu Abuja.

Iwadii fi ye wa pe ahesọ ni wọn kọkọ pe e tẹlẹ boya GNI ko nii jade nitori ariwo ti wọn ni Yayi atawọn eeyan ẹ fi gbode laimọ pe eegun to ba kọkọ jade jo, iran niru wọn maa n wo gbẹyin.

Ohun ta a tun gbọ ni pe wọn nijọba to wa lode yii naa gan an n fẹ ki ipo gomina wa lati ilẹ Yewa fun igba akọkọ,  ẹni ti wọn si sọ pe wọn ni lọkan lati fun ni tikẹẹti Gboyega Nasir Isiaka.

Ni bayii, wọn ni iṣẹ ti n lọ lọwọ lori bi GNI yoo ṣe ri tikẹẹti naa gba,bo tilẹ jẹ pe inu awọn ọba alaye kan ko dun si.

No comments:

Post a Comment

Adbox