Ẹgbẹ oṣelu Afican Democratic Congress, ADC, ti fi aidunnu wọn han lori ijanba ina kan to waye ni ọfiisi ijọba iyẹn sẹkiteriati, to wa ni Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, wọn ni bi igba to lọwọ oṣelu ninu ni.
Ati pe ṣe ni wọn fẹẹ fi iṣẹlẹ ọhun pa awọn alatako oṣelu lẹnu mọ, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ ninu ijọba dẹmokireesi ta n lo.
Ọrọ naa jade ninu atẹjade ti akọwe olupolongo ẹgbẹ naa lapapọ, Malllam Bọlaji Abdullahi fi sita.
O ṣalaye pe iṣẹlẹ ọhun waye ni ko pẹ tawọn fẹẹ yan awọn oloye ẹgbẹ kaakiri ipinlẹ naa.
O ni ibẹrubojo to mu ki wọn ṣe bẹẹ ko ju ti ibo gomina to n bọ lọna, eyi ti ẹgbẹ oṣelu ADC, ti ko idaamu ba wọn lataari bawọn araalu ṣe n fojoojumọ ṣe itẹwọgba ADC.
Abdulahi tun fikun ọrọ ẹ pe itiju nla lo jẹ fawọn to nigbagbọ ninu ijọba tiwa-n-tiwa ati ominira nidii oṣelu.
O sakiyesi pe iru iṣẹlẹ bẹẹ ko jẹ tuntun nitori bẹẹ ni iru fitinati bẹẹ ti n waye lawọn ipinlẹ bii Kogi, Kaduna, Kebbi, Eko ati Edo, nitori bawọn oṣelu apapọ ṣe kede pe ADC lẹgbẹ to le gbajọba lakooko yii.
O waa ni iṣẹlẹ Ekiti fi han daju pe gbogbo ọna ni APC fi n jowu ADC, ati pe ko si nnkan ti wọn le ṣe ti wọn fi le pawọn lẹnu mọ.
Abdulahi tun wa lo akoko naa lati ke si awọn eleto alaabo lati ṣewadii, ohun to ṣokunfa ijanba ina naa.
Bẹẹ lo ni gbogbo nnkan ti APC n ṣe ko di awọn lọwọ lati ma ṣeto ifilọlẹ awọn oloye ẹgbẹ ti wọn fẹẹ ṣe kaakiri ipinlẹ Ekiti.

No comments:
Post a Comment