IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday, 14 August 2025

KÀYÉEFÌ ŃLÁ : ÌJOBA ÌPÍNLÈ OGUN KỌ JALÈ LÀTI JẸ KÍ SOLOMON OSHO ṢE ÌPOLONGO ÌBÒ NÍ ÌLÚ REMO.


  Nise ni gbogbo awon to wa niwájú ilé ìwé girama tí ilu Remo n kọ haa!,Tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì lanu silẹ lai ma lè padé nígbà tí wọ́n rí bí oriṣiiriṣii moto Ọlọpaa ṣe n lọ tí ó sì ń bọ̀ láti rí i pe  Solomon Osho to je ohun díje dupò fun Ilé ìgbìmò asofin  láti agbegbe naa ko ri ìpolongo idibo rẹ se.
    

 Ṣáájú ,ni àwọn Ọlọpaa tíó tó bí ogójì ,tí kọkọ pàdé àwọn ogunlogo èrò tí ó tẹle oludije dupo náà ni ilu Iṣara, tí ó je ilu abínibí rẹ,tí wón sì kó jalè pe ko  le ri ìpolongo kankan ṣe nítorí pe ,awon ti gba ìpè láti òkè wa ,pe ẹnikẹni ko gbodo ṣe ìpolongo ibo kankan, yatọ si ẹgbẹ APC ni ilu naa lọjọ́ náà.
   Eyii to wa a jẹ kàyeéfì ju ni pe, nise ni àwọn Ọlọpaa to di ìhámọ́ra ogun yii ,to àga, tábìlì, kalopi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ di gbogbo oju títí tó lọ láti ilu Iṣara lọ sí Ijebu Rẹmo, tí wón sì kó jalè pe àṣẹ tí àwọn gba ni pé kí ẹnikẹ́ni ma ṣe gba ọna náà kọjá. 
    Ọpelọpẹ Ogbeni Rauf Aregbesola, to pa a láṣẹ fún àwọn olopa naa, nígbà tí ọkọ akọ- wọọrin rẹ dé ibi ìṣẹ̀lẹ̀ naa, pe kíá mosa kí wón kó àwọn 'panduku" tí wón kó sì ojú ọna kúrò ,kí wón sì jẹ ki olúkúlùkù bá tìrẹ lọ, nítorí pe títí ijọba ni wọn ti n fa idaduro ,ko si si ẹni ti o tọ fún wọn ní irúfé àṣẹ bẹ́ẹ̀.
     Logan ,tí àwọn Ọlọpaa náà foju kan Ogbeni Rauf ni wọn ti kọ ojú ibon wón silẹ ,tí wón sì bẹrẹ si ni ko gbogbo ohun tí wón kó sì ọna tẹ́lẹ̀ láti da Oludíje-dupò náà àti àwọn ènìyàn rẹ dúró kúrò lona, tí olúkúlùkù sí gba ìlú Rẹmo lo.
   

 Ìyàlẹ́nu ńlá ló tun wa jẹ́ fún gbogbo ènìyàn tí  ó tẹle Alàgbà Ọṣhọ ,nígbà tí wón tun de gbàgede ibi ti o yẹ ki wọn ti ṣe ìpolongo náà tí wón sì tún rí ọpọlọpọ ọlọpaa ti wọn ti dúró togun-togun tí wón sì tún yari kanle pe sẹẹ, ìpolongo ibo náà ko ni i waye nitori àṣẹ tí ó wà láti òkè ni pe ki awon ma ṣe fún ẹgbẹ miran laaye láti ṣe ìpolongo ibo ni oni ọjọ ,Ọjọbọ, Oṣù Kẹjọ ,odun 2025 ,ni ibi kankan ní agbegbe Ìjẹ̀bú nítorí ẹgbẹ APC nikan ni àwọn mọ to fi ìpolongo sì ọjọ náà .
    Nígbà tí akọròyìn ileeṣẹ wa fi oro wa Oga Ọlọpaa tí ó kó àwọn ọmọ iṣẹ rẹ sòdí wa si ibi ìṣẹ̀lẹ̀ naa ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fred Ode léèrè wipe kin ni ìdí pàtàkì tí àwọn Ọlọpaa fi pọ rẹpẹtẹ tibọn-tibọn nibi ìpolongo ibo tí wón sì kọ jalè fún Arákùnrin Solomon láti polongo ibo ni ó salaye pe, àṣẹ tí àwọn gba l'átòkè  ni pe ẹgbẹ oselu méjì kó lè ṣe ìpolongo ibo ni ojo kan náà,àsìkò kan-na àti ní ibi kan-na ni èèkàn ṣoṣo.

  Ìdáhùn ọkùnrin DPO yii lo wa mu ki aķọròyìn wa tẹ síwájú nípa ibere rẹ wipe kilo wà ṣẹlẹ̀ tí wón  ko fi  jẹ ki oludije dupò náà tí kuku dúró ní ìlú Iṣara tí wón ti kọkọ wa lè kúrò lati se ìpolongo rẹ̀, ṣùgbọ́n nise ni ọkùnrin Ọlọpaa náà fi ìbínú kúrò laarin awọn eniyan, ti o si n tẹnu mo pe,àṣẹ tí ohun gba lati  oke wa ni ki ẹnikẹ́ni tàbí ẹgbẹ kegbe  mase ṣe ìpolongo kánkán yatọ si ẹgbẹ APC, ti ko si si ohun ti ẹnikẹ́ni lè ṣe si i.

No comments:

Post a Comment

Adbox