Oludije fun ipo gomina nipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oselu 'Labour Party' ni ọdun 2023 Gbadebo Rhodes-Vivour ti bu ẹnu atẹ lu iṣakoso gomina Babajide Sanwo-Olu, o ni, pẹlu ogunlọgọ owo 'Gross Domestic Product' iyen igba o le ni aadota bilionu Naira, iyen 259bn, ti ìjọba ipinlẹ Eko n ri, ko ye ki ilu Eko wa bo ṣe wa yii.
Gbadebo salaye pe inu iṣẹ ati iya ni ọpọlọpọ ara ati ọmọ ipinlẹ Eko wa pẹlu aduru owo to n wọlé si apo ìjọba ipinlẹ naa.
O ni, ohun ti oju awọn ara ilu Eko n ri ko fi ara pẹ owo to n wọle sinu apo ipinlẹ naa, o wa a ni o yẹ ki iṣakoso Sanwo-Olu ṣe daadaa ju ohun to ṣe yii lọ.
Ni ko pẹ yii nibi ifilọlẹ eto 'Lagos Economic Development Update' (LEDU) ti ọdun 2025 ni wọn ti sọ pe GDP ipinlẹ naa ti to $259bn.
Bakan naa ni ipinlẹ Eko tun jẹ ipinlẹ ti okowo rẹ dara ju ni ile Afrika lẹyin ti wọn ba ti mu Cairo to wa ni ilẹ Egypt.
Gbadebo ni pẹlu owo yẹn, ibiti ipinlẹ Eko yẹ ko wa ko ni o wa yii, oni owo na ko han lara idagbasoke ilu Eko ati ninu eto ọrọ aje ipinlẹ naa rara.
Gbadebo ni owo ile ilu Eko, ọwọn gogo ni bii oju ẹja, ati gbe ilu naa gan-an ko rọrun, koda koto reẹ ni otun ati osi opopona yii, ki wa ni iwuri awọn.
Siwaju si i, Gbadebo ni eto abo gan-an tun mẹhẹ, gbogbo ọna lo dọti lọtun-un losi yii, awọn si ṣe ajọyọ.
Gbadebo salaye ohun ti awọn onile ilu Eko n fi oju awọn ayale gbe ri ti ìjọba ipinlẹ naa ko si ri ikankan ṣe si i.
O ni, loootọ ohun iyi ni pe GDP wa ni $259 biliọnu sugbọn ki wa ni ka ti gbọ pe ko han lara awọn olugbe ilu naa.
Gbadebo ni owo ọhun ko bọ sita, ko si ran eto ọrọ aje lọwọ, oni ọwọ awọn aṣayan ni owo naa wa wọn wa ni ki awọn maa ṣe ajọyọ.
O ni, titi di igba ti iya ko ba jẹ mekunnu mọ, ti ọmọ ẹru ba ṣe bii ọba, ti oúnjẹ ba di ọpọ, ti owo ile kuro nj ọwọn gogo, ti gbogbo ikan lọ etoleto, igba yii gan-an ni oun ṣe le yọ pe ilu Eko n gbooro.
Gbadebo rọ awọn eniyan pe ki wọn ni arojinlẹ daadaa lori eto idibo to n bọ yii.
No comments:
Post a Comment