Taofik Afọlabi
Gbajugbaja wolii nni, Prophetess Morẹnikeji Ẹgbinọrun ti ke gbajare pe awọn onijiibiti kan ti n fi orukọ oun lu jibiti lori ẹrọ ayelujara. Lasiko to n sọrọ yii, Wolii yii sọ pe ṣe lawọn oniṣẹ ibi yii lọọ gbe orukọ ati fọto oun sori ẹrọ ayelujara fesibuuku pe oun wa iranlọwọ owo lati fi pari ileejọsin oun. Ṣe lawọn onijibiti yii fi akanti ati orukọ wọn sori ẹrọ ayelujara yii pe ki wọn fi owo sinu akanti ọhun.
Ẹgbin Ọrun ni awọn eeyan kan ni wọn pe akiyesi oun pe awọn eeyan kan n fi fọto ati orukọ oun lu awọn eeyan ni jibiti lori ẹrọ ayelujara. Wolii yii fi kun ọrọ ẹ pe kẹnikẹni ma ṣe fun ẹnikan lowo lorukọ oun lori ẹrọ ayelujara, nitori pe oun ko tọrọ iranlọwọ fun kikọ ileejọsin oun lori intanẹẹti.
O ni ṣe lawọn eeyan naa fẹẹ lo anfaani bi oun ṣe gbajumọ ti Ọlọrun si n lo oun fun awọn eeyan fun itusilẹ lati fi orukọ oun ṣe gbajuẹ fun awọn eeyan.
No comments:
Post a Comment