Pelu ogbe okan ati ibanuje ni gbajugbaja onisowo, to tun je oloselu nla nipinle Eko, Onarebu Adedipe Dauda ti gbogbo eeyan mo si Ewe Nla, fi salaye ohun to ju e ri lahaamo awon olopaa, nibi to ti le ogoji ojo din die lori esun ti ko mowo-mese.
Gbajumo onisowo to ni ileese Adedas Develepment Foundation salaye fun akoroyin wa pe awon ota oun nidii oselu, ti eru n ba pe oun yoo fidii won janle lasiko ibo to koja yii ni won gbimo po pelu awon agbofinro lati fesun ka oun pe oun ni baba isale awon a- ji-epo wa ti won fa ijamba ina to sele ninu osu kejila odun to koja ni Abule-Egba.
Ewe Nla to tun je eleyinju aanu so pe boun se ri i pe a won olopaa ti gbe oruko oun sinu iwe iroyin pe won n wa oun loun gba ileese won to wa ni Ikeja lo lati mo idi ti won se n wa oun ati ese ti oun se.
O fi kun oro re pe bi oun se debe ni won ti oun mole pelu awon ti won ti mu, ti won si beere lowo awon eeyan ti won mu yii boya won mo oun ri tabi oun lo n ran won nise, sugbon meji ninu won so pe awon ko mo oun ri, bee loun ko si lara awon, sugbon merin ninu awon so pe awon mo oun gege bii ololselu ati eni to maa n ran awon to ku die kaato fun lowo lawujo.
Okunrin yii ni bo tile je pe awon afunrasi ti won mu yii so pe oun ko si lara awon sibe, oga olopaa ipinle Eko nigba naa, Ogbeni Imohim Edgahi, so pe ki won fi oun pamo, toun si lo ogoji ojo din die lahaamo awon olopaa yii.
O ni bi won se fi oun pamo sahaamo yii sakoba fun ipolongo oun gege bii asofin to fee soju awon eeyan Alimosho 1 nile igbimo asofin Eko, ibo ku ojo meji lo so pe won fi oun sile, eyi to pa erongba oun lati soju awon eeyan oun nile igbimo asofin.
‘E wo o, bi won se ti mi mole, ti won paro ohun ti mi o se mo mi lowo kan oselu ninu, mo mo ibi ti isoro mi ti wa, eru lo n ba awon alatako mi nitori pe awon eeyan feran mi, ohun to je ki won puro mo mi niyen, sugbon Olorun ju eda lo.
No comments:
Post a Comment