Gongo yoo so lojo keji, osu karun-un, odun yii niluu Ibadan, nipinle Oyo. Ojo naa ni Olubadan, Alayeluwa Oba Saliu Adetunji Akanmu Aje Oguguluso Akoko, yoo fi ilu mo on ka osere fuji nni, Alaaji Abass Qudus Akande Obesere ati iyawo e, Arabinrin Tolanikawo Abass joye Agbaakin Abobagunwa ati Yeye Agbaakin Abobagunwa tile Ibadan.
Gbongan 'Kakanfo Inn', to wa ni Ring Road, niluu Ibadan layeye naa yoo ti waye. Awon olola, olowo atawon eeyan pataki lawujo ni won reti nibi ayeye iwuye naa.

No comments:
Post a Comment