Ohun to sele ni pe lojo ayeye ojoobi osere omo bibi ilu Ilaro, nipinle Ogun yii lawon omoose e yii loo ka mole laaro kutukutu pelu akara oyinbo ati ebun nla nla. Bi won se de ile e ni won korin fun un, lokunrin naa ba sare bo sile lati oke ile e yii lati mo ohun to n sele, asiko naa lo mo pe won fee wa ba oun sajoyo ayeye ojoobi oun ni, ni won ba bere si ni i ya awon foto ile yii ti won n ju u sori ero ayelujara.
Ninu oro Mega 99 lo ti dupe lowo awon omoleyin e fun ife ti won fi han soun, o ni bo tile je pe oun ko fe koro ile naa di ariwo tawon eeyan yoo maa polongo e, sugbon bawon eeyan oun se so o sita yii, ko si ohun ti oun yoo se si ju pe koun gba ohun ti won se lo.
Milionu lona ogorun-un meji naira le la gbo pe Mega 99 na lori ile yii, lati orile-ede Italy lo ti ra gbogbo ohun ti won lo sara ile naa.
Ojutole naa ba Mega 99 dupe lowo Olorun fun oore ayo yii, oore naa ko ni i taku sibe.
.
.
No comments:
Post a Comment