IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday 18 March 2019

OPE O:BABA SUWE TI FI ESE E RIN, KO NI I PE E LO SILUU OYINBO


Iroyin ayo to te wa lowo bayii ni pe gbajumo osere apanilerin-in nni, Alaaji Nurudeen Babatunde Omidina tawon eeyan mo si Baba Suwe ti fi ese e rin, ara okunrin naa ti n ya, o ti fi opa to n fi n rin sile patapata, ese ara re lo fi n rin bayii.

Ojutole gbo pe eto ti n lo lowo bayii bi okunrin omo bibi ilu Ikorodu naa yoo se lo siluu oyinbo fun ise abe ti won se fun un yii.

Pelu iduunu lawon eeyan e atawon asaaju egbe osere tiata Yoruba to n je TAMPAN fi gba minisita eto ilera lalejo lodo Baba Suwe lonii. Minisita yii lo pase fawon oga ileewosan  ijoba 'LUTH' to wa ni Ikeja pe ki won fun Baba Suwe nitoju to peye lofee, ko too di pe y

oo loo sise abe nilu oyinbo. 

No comments:

Post a Comment

Adbox