IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 16 September 2018

KAYODE SALAKO TU ASIIRI BI OYUN OSU MARUN-UN SE BAJE LARA FOLUKE DARAMOLA NIBI IPOLONGO IBO AMBODE

Latowo Taofik Afolabi
Alaakoso fun ajo 'Buhari/ Osinbajo Mandate Group', iyen  ajo to n ri si bi saa keji  yoo se e bo si  Aare Muhammed Buhari lowo nile Yiruba, Ogbeni Olukayode Salako,ti tu asiiri bi oyun osu marun-un se baje mo iyawo e, Foluke Daramola Salako lara nibi ipolongo ibo Ambode lodun 2015.

Okunrin yii, to tun je oludasile ileewe 'Bosworth International  College' so pe lojiji niyawo oun daku nibi ipolongo Ambode lati wole gege bii gomina ipinle Eko, ti oyun osu marun-un to ye ko je omo akoko ti osere naa yoo bi foun baje.

O ni pelu wahala ati ilakaaka iyawo lori ibo to gbe Ambode wole yii, ko si anfaani kankan ti gomina se fawon, bi bee ko, se lo ko ipako sawon, tawon ko si anfaani kankan je lara e.

Salako fi kun oro re pe gbogbo awon eeyan ti won sise fun Ambode lati di gomina lokunrin naa keyin si nigba ti agbara ijoba dowo e tan. 

O te siwaju ninu oro re pe pelu bi Ambode ko femi-in imoore han sawon yii, sibe oun ati iyawo si maa ranti e ninu emi.

No comments:

Post a Comment

Adbox