IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 25 September 2018

ILEESE 'YATNIY COMMUNICATION INTERNATIONAL' FEE SAYEYE ODUN ASA NI CANADA

Okan pataki ninu awon ileese to n gbe asa laruge kari aye, nileese Yatniy Communication
OYATOYE LO GUNWA SOFIISI E YII
International to wa lorile-ede Canada. Ohun ti Ojutole-toko ri gbo ni pe ileese naa ti Ogbeni Joel Olaniyi Oyatoye, je oludasile e fee sayeye ayajo odun Asa.
Gege bi a se gbo, ojo kesan-an ati ojo kokanla inu osu kokanla odun yii ni won yoo sayeye naa. Ilu Winnipeg ni won yoo ti se e lojo kesan-an, nigba ti ilu Toronto yoo gbalejo ayeye yii lojo kokanla odun yii. 
A ri i gbo pe won fee lo ayajo odun asa yii lati fi gbe asa wa laruge, lati fi safihan awon ohun isembaye ti Olorun fi jinki wa nile adulawo. 
E gbo ohun ti Oyatoye wi ' A fee lo ayajo odun asa yii lati je ki gbogbo aye mo pe nnkan gidi ti Olorun fun wa, a fe ki won mo pe ede wa , asa ati igbe aye wa lo dara ju . 
Awon eeyan nla, awon osere, awon olorin, akewi atawon eeyan jankan-jankan lawujo lati orile-ede Naijira atawon ilu mi-in l'Afrika la n reti nibi ayeye yii.
Bakan naa la o tun fun awon eeyan ti won kopa pataki fun ilosiwaju asa ati ede lami-eye lati fi se koriya fun won. Gbogbo awon eeyan ti oro iran Yoruba ba je logun la n reti nibi ayeye asa yii'   

OYATOYE ATI OYINBO ARA CANADA

No comments:

Post a Comment

Adbox