Oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADP nipinlẹ Eko, Babatunde Ọlalere Gbadamọsi tọpọ mọ si BOG ti sọ pe ijọba Baba sọ pe ti wọn n lo nipinlẹ Eko ti su awọn araalu wọn si ti sun wọn mọ ogiri, idi niyii ti won fi n wa ẹgbẹ oṣelu ti yoo jẹ ọna abayọ nibi ibo to n bọ lọdun 2019 ti yoo le APC danu.![](https://blogger.googleusercontent.com/img/b/R29vZ2xl/AVvXsEgV4voLti4aSaa8Flf_BHgUnBbBH0xlNIl-uXgGY_2bG_gKenLkMk4F13T8NKjFLZ1oBkpvquof6_62E1ohBwJiKFt986WfF4wleRfW5KNOnHNUhPvZ4hazT8LrovXEkhqlxTZjUYaYEeZX/s320/IMG-20180822-WA0022.jpg)
![](https://blogger.googleusercontent.com/img/b/R29vZ2xl/AVvXsEgV4voLti4aSaa8Flf_BHgUnBbBH0xlNIl-uXgGY_2bG_gKenLkMk4F13T8NKjFLZ1oBkpvquof6_62E1ohBwJiKFt986WfF4wleRfW5KNOnHNUhPvZ4hazT8LrovXEkhqlxTZjUYaYEeZX/s320/IMG-20180822-WA0022.jpg)
O sọrọ yii lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ nibi ipade tawọn oloye ẹgbẹ ADP nilẹ Yoruba ṣe, eyi to waye niluu Eko. O sọ pe ijọba ti wọn n lo lati nnkan bi ogun ọdun sẹyin lo ti su awọn eeyan, bo tilẹ jẹ pe o tipẹ ti wọn ti fẹẹ le wọn danu ṣugbọn ojooro ati awọn iṣẹ ibi tawọn to wa nijọba naa n ṣe ko jẹ.
Gbadamọsi sọ pe lọdun 2003, ni wọn ti kọkọ fẹẹ fi ibo le wọn danu nigba ti ajo eleto idibo nigba naa ti kọkọ kede pe Funṣọ William’s lo wọle ṣugbọn nigba tilẹ ọjọ keji yoo fi mọ, wọn ti ṣojooro pe awọn lawọn wọle pada ẹlẹẹkeji.
O ni iyẹn tun lọ, lọdun 2007, tawọn araalu tun mura silẹ lati jẹ ki Funṣọ William’s wọle, ṣe lawọn ẹni ibi da ẹmi ẹlegbodo, awọn eeyan wa sọ nigba naa pe awọn ko mọ ẹni to pa ọkunrin naa ṣugbọn idahun temi maa n fun wọn ni pe awọn to jere nipa iku ẹ ni ki wọn roo si.
O tun ṣalaye pe ipo to yẹ ki ipinlẹ Eko wa kọ lo wa a, bi a ba ni ka a sọ nipa eto ọrọ aje atawọn idagbasoke, ṣugbọn o ni, nigba to jẹ pe awẹn ẹbi kan ni wọn fẹẹ maa paṣẹ, ki aṣẹ gbogbo ipinlẹ Eko wa lọwọ wọn, o ni asiko ti wa to tawọn araalu ṣetan lati fi ibo le wọn danu. Ko si nnkan to n jẹ babakresi tabi baba sọ pe mọ.
Oludije naa tun ṣalaye siwaju pe ẹgbẹ ADP ipinlẹ naa ti mura silẹ fun yiyan awọn oludije ti wọn yoo dije labẹ ẹgbẹnaa, o ni gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ ni wọn yoo ṣe ojuṣe wọn lati dibo fẹni to ba wuu, o ni ẹgbẹ naa ti kọja, ẹni ti yoo maa fowo ra ibo lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ.
O ni bi awọn ọmọ ipinlẹ Eko ba le fun ẹgbẹ oṣelu ADP laaye lati jawe olubori ninu ibo gomina to n bọ naa, gbogbo nnkan tawọn fẹẹ ṣe lati le jẹ ki ipinlẹ ọhun ba tawọn agbaye yooku mu, ko gba wọn ju ọdun kan lọ, nitori awọn ti ko to Eko lagbaye, o nibi ti wọ de bayii.
Ati pe awọn iṣoro ti ko yẹ ko maa dojukọ wa bii omi, ina, atunṣe oju popo lawọn araalu n dojukọ pẹlu bi owo ṣe n wọle, bakan naa, lo ni eto ibanisọrọ wa gan-an ko ja geere to, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ, o wa beere pe iru ijọba wo wa ni a n lo nipinlẹ Eko.
Ọpọ awọn to n ṣakoso ipinlẹ Eko lo sọ pe o yẹ ki wọn wa nibi ti wọn ti n tọju ṣugbọn ni bayii, o ni opin ti de ba iru awọn aṣaaju bẹẹ nitori wọn ti sun awọn araalu kan ogiri, ohun ti wọn wa ni ijọba tuntun ti yoo le ṣe gbogbo nnkan ti wọn ba n fẹ, ti ko ni si pe wọn fi ara ni araalu.
O wa sọ pẹlu idaniloju pe ireti ṣi wa fun ẹgbẹ oṣelu ADP lati gba akoso ipinlẹ Eko, nitori ariwo ayipada rere ti ki i ṣe ti APC lawọn araalu pariwo bayii.
.
No comments:
Post a Comment