IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 30 June 2018

Bi Olorun se ko gbajumo osere fuji, Obesere yo ninu ijamba tanka epo to paayan repete lojuona marose Eko si Ibadan ree



Taofik Afolabi

Titi dasiko yii ni ilu mo-on ka osere fuji nni, Alaaji Abass Akande Obesere, si n dupe lowo Olorun fun bo se ko o yo ninu ijamba tanka epo to paayan repete lojuona- marose Eko si Ibadan lojo Tosde to koja yii.

Gege bi a se gbo, ibi ifilole ajo kan ti won pe ni 'Ewa inu Foundation' ti Arabinrin Abimbola Omotayo, iyen iyawo gbajumo sorosoro ori telifisan, Soji Omotayo, sagbeteru e lObesere se wale lati ilu London to wa lati bii osu meji seyin. 

Bi agba osere fuji ti won tun n pe ni Alaaji Agba tuntun yii se bale si Naijiria lawon amugbalegbe e ti so fun un pe ko tete maa lo sile igbafe 'Airport Hotel' to wa ni Ikeka tayeye naa ti waye, oun naa ko si ko ohun ti won so yii, ara tanka epo to gbina yii ni moto Obesere gba koja, ko si ju iseju marun-un to koja tina nla fi seyo lara oko agbepo to fopo emi sofo yii. 
  
Se lObesere atawon eeyan e ti won wa ninu moto yii dupe fun Olorun pe o gba emi awon la, bee losere omo bibi ilu Ibadan yii banuje lori isele yii, nitori e gan-an ni ko se yoju sibi ti won ti sayeye yii,  nitori pe oga awon sorosoro to dari ayeye yii, Ambasado Yomi Mate ti gbogbo aye mo si Ifankaleluya, ti koko kede pe Obesere n bo nibi ayeye yii, sugbon ijamba yii ba a lokan je pupo.  

No comments:

Post a Comment

Adbox