IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 25 February 2025

Mi o bawọn ta ilẹ ilu ri latigba ti mo ti wa lori itẹ- Olu Itori


 

Olu tiuu Itori, Ọba Abdul-Fatai Akorede Akamọ, ti sọ pe oun ko bawọn ta pilọọti ilẹ to kere, depodepo pe oun yoo ta nla niluu Itori latigba toun ti gori itẹ awọn babanla  oun ati pe ijọba lo ni awọn ilẹ ti aawọ wa lori ẹ,  koda aafin oun wa yii, ilẹ ijọba lo pe.

 

O sọrọ yii lakooko to n ṣe ipade pọ pẹlu awọn oniroyin fun ti ayẹyẹ ọdun kọkanlelogun, to ti gori itẹ awọn babanla ẹ, eyi ti wọn ti bẹrẹ.

 

Kabiyesi sọ pe ẹni to ba mọ pe oun loun nilẹ to ni aawọ ninu naa ki wọn jade pẹlu ojulowo iwe ilẹ C of O.

 

O sọ pe " Laitgba ti mo ti gori oye, mi o ta abọ piọọti ilẹ rii, Mo ti fawọn eeyan ni ilẹ ọgbọn eeka lọfẹẹ daadaa.Gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ si wa oore-ọfẹ, eeyan ki I ba Ọlọrun jijakadi. A ni lati ṣe fawọn eeyan pada’’.

 

Nigba  to sọ awọn eto ti wọn ni nilẹ fayẹyẹ ọhun lo ti sọ pe awọn yoo sanwo fawọn ti ara wọn ko da ti wọn wa nile iwosan. Bẹẹ lo ni awọn eto mii-in tun wọn bii eto ẹkọ ọfẹ, riro awọn ọdọ lagbara atawọn nnkan mii-in.

 

Ọba Akamọ sọ pe awọn ọmọleewe poli ICT, Itori, ti wọn jẹ ogun ni wọn yoo jẹ anfaani eto ẹkọ ofẹ, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira, ẹnikọọkan, bẹẹ lo ni oun yoo sanwo ọṣibitu fawọn tara wọn ko ya ti wọn da duro ni ọsibitu jẹnẹra to wa ni Ijaye ati Sacread Heart, to wa niluu Abẹokuta.

 

O fikun ọrọ ẹ pe awọn yoo tun nawọ sawọn to wa ni ọgba atunṣe Ibara, ti wọn ko ri owo beeli wọn san. Bakan naa lo ni ile awọn ọmọ ti ko niya iyẹn Stella Obasanjo Orphanage home’’ naa ko ni gbẹyin lara awọn ibi ti wọn yoo ṣabẹwo de.

 

 

 

Ọba Akamọ wa fi akoko naa gba awọn ọdọ lamọran lati jẹ aṣoju rere, nitori idi eyi lawọn ṣe nnkan ti yoo mu wọn niṣẹ niluu, nipaṣẹ ironilagbara ti wọn fẹẹ ṣe fun wọn.

 

O waa gboriyin fun Gomina Dapọ Abiọdun lori igbiyanju ẹ fun idagbasoke imayedẹrun to ṣe siluu Itori. O ni o ti fi apẹẹrẹ lelẹ lati sọ ẹgan dofo lori ọna Itori- Ewekoro si marosẹ Eko.

No comments:

Post a Comment

Adbox