Ara
ọtọ gba a ni gbajugbaja ati ilu mọ-ọn ka pedepede ori radio ati
tẹlifiṣan nni, Ambasadọ Yọmi Mate ti gbogbo aye mọ si Ifa-n-kalle-luyah
mu wọ gbogbo awọn eto to n ṣe lori redio. Ohun tuntun ti gbajugbaja
sọrọsọrọ naa ti wọn tun n pe ni Aniyikaye mu wọ awọn eto ẹ ọhun ni yoo
mu anfaani nla ba gbogbo awọn eeyan patapata.
Gẹgẹ
bi Ojutole ṣe gbọ, anfaani yoo wa fun awọn eeyan lati ki awọn eeyan wọn
ti wọn n ṣe nnkan rere bii ayẹyẹ ọjọọbi, isile, oye jijẹ, igbeyawo, oku
agba, bẹẹ ni anfaani yoo wa fun awọn eeyana lati ranti awọn ẹni wọn to
ti d'oloogbe lori awọn eto yii lowo ti ko gara.
Ilana mẹta ọtọọtọ ni Ifa ti wọn tun n pe ni Ẹbọra Ọmọ to n gbe inu redio dun yanmu-yanmu pin ilana ikinni naa si.
Akọkọ ni di darukọ ẹni ti wọn fẹẹ ki yii lori eto ẹ.
Elẹẹkeji
lo pe ni ‘VIP Wishes’ Ninu eyi ni yoo ti darukọ ẹni yii, ọkọ tabi iyawo
atawọn ọmọ ẹni naa pelu alaaye ati apejuwe ranpe nipa onitohun; fun
apẹẹrẹ, a n ki Ọgbẹni Taofik Afọlabi, Baba Abdulmalik, olowo ori Hajia
Mọrufat ku oriire ayẹyẹ ọjọọbi wọn to waye... Bẹẹ si ni anfaani wa lati
darukọ ẹni to ṣagbẹrẹru ikinni ohun.
Ẹlẹẹkẹta
ni ‘Royal Wishes’ Eleyii lo gbara ju gbogbo awọn ikinni yooku lọ, ninu
ikinni yii ni yoo ti darukọ ẹni to fẹẹ ki yii, ileeṣẹ ẹ, awọn ọmọ ati
iyawo ẹ, papanbari ẹ ni pe wọn yoo ki ORIKI ILU/IDILE ẹni yii ti Ori oun
funra paapaa yoo wu nibikibi to ba wa.
Awọn ileeṣẹ redio ti "Ifankalleluyah" ti n ṣe awọn eto ẹ lọsọọsẹ niyii:
Lọjọ Isẹgun Tusde - Ade'le-ba're lori redio Bond FM 92.9 Ikeja, lati aago mẹrin aabọ si aago mẹfa ku isẹju mẹẹẹdogun nirọlẹ
Ọjọruu Wesidee – ‘Owambe Special’ lori redio Fresh 107.9 FM Abeokuta, lati aago meji ọsan si aago mẹta aabọ.
Ọjọbọ Tọsidee - Ko Maa Flow lori redio Faaji 106.5 FM Alagbado lati aago meji ọsan si aago mẹrin ọsan.
Ẹnikẹni to ba fẹẹ ki awọn eeyan ẹ lori gbogbo awọn eto yii, ko pe Ambasadọ Yọmi Mate Ifankalleluyah sori awọn nomba wonyii:
0803 376 6552
0807 450 0685
0802 311 9962(WhatsApp).
No comments:
Post a Comment