Lasiko to n ba wa soro, o ni Ogbeni Babajide Sanwo-Olu ni yoo wole gege bii gomina nipinle Eko. Sat Guru Mahaji j ni nnkan nla ni Asiwaju Bola Ahmed se fawon ara Eko pelu bo se fa Sanwo-Olu sile gege bi oludije ipo gomina labe egbe oselu APC.
O ni didun losan yoo so fun Sanwo-Olu lojo Abameta, Satide to n bo yii.
Ni tipinle Oyo, baba yii so pe Bayo Adelabu ni kawon ara Oyo dibo fun lati fi san oore ti baba re Adegoke Adelabu se fun iran Yoruba. O ni kawon ara Oyo fokan bale, Adelabu ni gomina won.
Guru Mahaji j ni boya tabi sugbon ko si nibe, egbe APC ni yoo wole nipinle Ogun, nitori aburu nla ni yoo je ki eni ti Amosun fa sile wole gege bii gomina naa.
O salaye siwaju si i pe ohun ti Amosun se fun Buhari lasiko to loo polongo ibo nipinle Ogun ko bojumu rara, nitori pe se lo dabii igba ti omo ba juko fun baba e ni, eyi ti ki i sele nile Yoruba. O ni gbogbo awon ipinle ti ki i se ti egbe APC ni won ti sayesi fun aare, ohun to buru ni pe ipinle Ogun to je pe APC lo n dari ni won ti juko fun aare.
O fi kun oro re pe oju gbodo di Amosun nigbeyin pelu ohun to se yii.

No comments:
Post a Comment