Ojo nla ti okan pataki ninu awon osise ileese Radio Lagos, Adeola Kifayat Orisile, ko ni i gbagbe boro lojo Abameta, Satide to koja yii, idi ni pe ojo naa ni won jawe oye le arewa obinrin naa lori gege bii Erelu Afedesewa ilu Oruba Awori Ota. Tilu-Tifon ni won jawe oye le oloye tuntun lori laafin Oba, leyin e ni won gbe ayeye nla yii lo si gbongan 'Maridon', nibi togun-logo awon eeyan pataki lawujo ti ba obinrin daadaa seye nla naa.
Eni to ba wa nibi gbongan yii lojo naa, yoo ro pe oba ilu tabi apase ilu kan lo n sayeye nni, pelu bi gbogbo inu gbongan yii se kun fofo, eni to ba debe nikan lo le royin.
Ojo yii ye Adeola, adura wa ni pe ki emi Iya Oloye gun ninu owo, ola, a
lubarika ati igbega repete.
No comments:
Post a Comment