IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday 5 November 2018

OKU OLOMO:AWON AAFAA ROJO ADURA NIBI ADURA OJO MEJO MAMA RASHEED SOLAQ N’IBAFO

Bii omi lawon eeyan ri nibi adura ojo mejo mama alase ati oludari ileese Solaq Spiritual Home, Alaaji Rasheed Solaq to waye lojo Eti, Fraide to koja yii. Pitimu lawon, ara, ojulumo atawon afenifere peju-pese nibi  adura ojo mejo fun mama naa, Alhaja Afusat to jade laye leni odun metadinlaadorun-un (87).

Ilu Ibafo, nijoba iibile Obafemi Owode, nipinle Ogun leto adura ohun ti waye, nibi ti awon Alfaa nla nla ti pejo lati seto pataki ohun.
Lara ohun to tun waye lojo naa ni irun Jimo ti won koko ki, ki adura fidau ohun too bere. Bo tile je pe ko si mosalasi Jimo nile 
ohun, sibe, won kirun jimo nibe, niwon igba ti awon Musulumi to wa nibe lojo naa ti po daadaa niye, tawon Afaa nla nla si ti wa nibe pelu.

Saaju ojo naa ni won ti sin mama naa nilana esin Islam ni kete to jade laye
Ninu oro Solaq lo ti sapejuwe mama naa gege bi abiyamo tooto, ti igbaiyanju e lori omo ko lafiwe rara. O ni, “Titi aye la o maa ranti mama wa, nibi ti awa omo de loni-in; Olorun ni o, bee lo mo on mo fi iya to bi wa salatileyin fun wa. Abiyamo to maa n de omo ladeesi ni won. A si dupe wi pe Olorun fun won
ni emi gigun, bee lawa naa gbiyanju lati toju won daadaa, bo tile je pe eyi ti awa se, ko to ida kan ninu ohun ti awon obi se fun wa, lori ki a le wa saye, ati ki a le je eeyan. Ki Olorun ba wa se alujona onidera fun Alhaja wa.” Solaq lo so bee.

Lara awon omo to gbeyin mama yii ni Isiaka, Ramota, Alhaji Rasheed Solaq ati Rasheedat atawon iyawo, pelu awon omo omo.



No comments:

Post a Comment

Adbox