Ojutole ri gbo pe ohun to fa ija laarin won ni etaanu ati orogun owo ati pe owo won tun n kan owo lodo awon eeyan ti won je ololufe won, ti won nawo fun won.
Yato si eyii, a gbo awon mejeeji ko gba fun ara won lori eni to je asaaju, bi Ayeloyun se n so pe ogaa loun je fun Saoti Arewa lagboole orin, bee ni Saoti naa je ko ye e pe oun ki i se majesin nile odu.
Koda, a gbo pe awon osere meji yii tun maa korin bu ara won lode ariya ati ninu awon orin won. Bo tile je pe awon eeyan kan gbiyanju lati yanju wahala yii, sugbon won ko ri i yanju di bi a se n soro yii.
Ohun to daju saka ni pe wahala nla lo n sele laarin Saoti Arewa ati Ayeloyun.
No comments:
Post a Comment