IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday, 11 October 2018

OPE O: BASHIRAT OMO ALUBARIKA, OLORIN ISLAM ATOKO E, AKOLADE ABDULGANIY SOMO LORUKO

Anaa, ojo Wesde, lokan ninu awon olorin islam lorile-ede yii, Hajia Bashirat Abdulkareem tawon eeyan tun mo si Omo Alubarika tabi Aseyege 1 atoko e, Sheik Akolade Abdulganiy somo tuntun ti Olorun fi tawon lore loruko. Ile won to wa l'Oworosonki, nipinle Eko layeye ikomo naa ti waye.
Die lara awon oruko ti won so omo tuntun jojolo yii ni: Multaqa   Oloruntooyin Oluwatimileyin Aduradire Ayinde Mustapha Ademide. Bamubamu lawon ebi, are, ore atawon afenifere kun ibi isomoloruko yii.

Lara awon olorin Islam ti won fojo naa ye Bashirat atoko e si ni: Alaaji Sulaiman Sarafadeen tawon eeyan tun mo si Albushrah, Haji Kola Adinni ati Haji Imole Anobi. Aremo Kabieesi Owuro la wa, Sunday  Adewoye ati olorin takasufee, Quibow naa wa nibi ayeye yii.Die lara foto ti Ojutole mu wa fun yin nibi ayeye o naa ree.

Awa naa ba Bashirat dupe lowo Olorun fun oore ayo to se fun un yii,omo naa yoo lalubarika, yoo soriire. 


























No comments:

Post a Comment

Adbox