Agnes Funshọ Akinlẹyẹ,oludije fun ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun, labẹ ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress iyẹn NDC ti sọ pe pataki ojuṣe fun ẹni to ba wa nipo oṣelu kan tabi omiin ni lati sin awọn to ba ṣoju fun, idi ti wọn fi dibo fun niyẹn.
O ni onitọhun si gbọdọ jẹ aṣoju rere ti yoo fọwọsowọpọ pẹlu awọn akẹgbẹ lati le mu ipinlẹ tabi orileede tubọ dagbasoke.
Idi si niyi toun fi pinnu lọkan oun lati jade dupo gẹgẹ ọmọ ile igbimọ aṣọfin nipinlẹ Ogun, o ni ko si nnkan mii bi ko ṣe lati sin awọn toun fẹẹ lọ ṣoju fun.
Obinrin naa sọ pe pẹlu awọn iriri toun ti ni lo mu ki oun jade, toun si mọ pe bi wọn ba dibo yan oun wọle,Ifọ keji yoo tubọ gbooro si.
O ṣalaye pe Ifọ keji wa lara awọn to mule tipinlẹ Eko, idi niyi to fi yẹ kawọn igbesẹ kan wa ti yoo mu inu awọn agbegbe naa dun, ti wọn yoo fi ni irọrun.
O sọ pe loorekoore loun yoo ma wa mu abọ jẹ awọn eeyan ẹ lori ibi to ba ba nnkan de nibi to ti n ṣoju wọn.
O ni ọpọ awọn adugbo kan ni wọn ni ipenija kan si keji, ti oun yoo gbe igbesẹ lati wa ojutu si nile igbimọ aṣofin.
Funshọ ṣalaye siwaju pe, "Loootọ ni mo jade lati dupo ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun labẹ ẹgbẹ oṣelu NDC, eyi ti mo gbadura pe Ọlọrun yoo ran mi lọwọ lati debẹ gẹgẹ bi aṣoju rere fawọn eeyan mi.
"Ṣugbọn mo mu dawọn eeyan mi loju pe bi ilọsiwaju ati idagbasoke yoo ṣe de bawọn ni maa mu ni ọkunkundun."
O ṣalaye pe ọpọ awọn eto loun ni fawọn eeyan Ifọ Keji ti yoo mu irọrun ba wọn, paapaa lati wa ọna abayọ sawọn iṣoro to n doju kọ wọn.
Oludije NDC ọhun wa lo akoko naa lati rọ awọn obinrin akẹgbẹ ẹ lati dide gbaruku ti oun lati le jawe olubori ninu ibo ọhun pẹlu ileri pe oun ko ni jawọn nitanmọ.
O sọ pe gbogbo wa la mọ pe akoko ipolongo ko tii bẹrẹ, nitori idi eyi loun ko ṣe tii le mẹnuba awọn nnkan to ni lọkan fawọn araalu.
Bẹẹ lo tun fi idunnu ẹ han lori bi ẹgbẹ oṣelu NDC, ṣe fojoojumọ gbilẹ si nipinlẹ Ogun pẹlu idaniloju pe awọn ni yoo jawe olubori ninu ibo ọdun 2027.
O ni ẹgbẹ NDC ti gbogbo araalu ni, Ọlọrun fẹẹ lo lati gba awọn eeyan kuro ninu ijọba to wa lode yii, nipasẹ ibo ọdun to n bọ naa.

No comments:
Post a Comment