IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday 23 March 2024

Ìjọ ‘Istijabah Du'ah’ ṣe waasi ààwẹ̀ ramadan ní Ìdíròkò ni ìpìnlẹ́ Ògùn


Ijọ Istijabah Du'ah(Idmon)ti ori ijọ wọn wa nilu Idiroko nipinlẹ Ogun ṣe waasi Ramadan ọdun yii lọjọ Abamẹta, Satide ọsẹ to kọja labẹ oludasilẹ ijọ naa,Sheik Abdul-Ganiy Ajibade Akewuṣọla ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Ọlọrun nidahun adura.

Waasi tọdun yii ni ẹlẹẹkẹsan- an iru ẹ ti akọle tọdun yii si jẹ ‘ayo ọkan,Sheik Basit Ọlanrewaju Katibi Bello Apọnle Anọbi lo ṣe waasi lọjọ naa nigbati Alaaji Oyeniran jẹ olugbalejo.

Lasiko ti imaamu Nasirudeen to jẹ miṣanna ijọ naa n ba wa sọrọ lo ti dupẹ lọwọ awọn ọmọ ijọ fun ifarajin ati igbẹkẹle wọn ninu Ọlọrun, bẹẹ lo dupẹ lọwọ oludasilẹ ijọ Istijabah kaakiri iyẹn, fun bo ṣe nawo nara lati jẹ ki waasi  yii maa waye lọdọọdun.

Awọn ọba alade to wa nibẹ lọjọ naa ni Onipokia ti Ipokia, Ọba Oluṣọla Ọlaniyan atawọn ori ademi- in.

 

No comments:

Post a Comment

Adbox