IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday 18 December 2023

Ileese ADRON Homes derin peeke awon oniroyin,Moto boginni, Ero alagbeletan ati ero ibanisoro ni won fi sefa je



Lati femi imoore han sawon oniroyin to n gbe ileese won laruge lati ibere odun yii, ogbontarigi ati oga nla ninu awon ileese to n ta Ile lorileede yii, Adron homes and properties derin peeke awon oniroyin pelu ebun agbayanu.

Nibi ayeye ipari odun ti ileese naa se lati fi se koriya fun awon oniroyin lawon oniroyin meta kan ti gba ebun rabanda fun bi won se tayo laarin awon  elegbe won ninu gbigbe ileese ADRON Homes laruge.

Moto obokun oloye ni eni to se ipo kin in ni gbe lo sile, nigba ti eni to se ipo keji gbe ero alagbeka ti won n pe ni Mac book lo sile ni tie. Foonu tiye re le ni milionu kan Naira iyen I phone 13ni eni to se ipo keta fi se ifa je ni tie.

Yato si awon meta yii, gbogbo awon oniroyin ti won wa nibi ayeye naa ni won gbe apo raisi nla, adiye meji ati ororo lo sile won lati fi sodun Keresi ati odun tuntun.

Ninu oro oga-agba ileese ADRON Homes, Aare Adeola Emmanuel King, lo ti so pe Igbe aye to rorun fawon oniroyin lo je ileese ADRON login. O ni oun mo riri ipa ti awon oniroyin n ko fun idagbasoke ati ilosiwaju ileese ADRON Homes.

Oloye nla yii fi kun oro re pe erongba ileese oun ni lati je ki gbogbo awon oniroyin di eni ti yoo maa fi moto sese rin. Jije ati mimun ni won fi kase ariya opin odun naa nile.

Ohun to daju saka nipe yoo pe e daadaa kawon oniroyin too gbagbe ojo yii.

No comments:

Post a Comment

Adbox