Ọjọ nla ti gbogbo awọn eeyan ilu Ibeshe, niluu Ikorodu ati agbegbe rẹ ko ni i gbagbe bọrọ lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, ọjọ naa ni ọba ilu naa, Alayeluwa Ọba Ọba Richard Abayọmi Ogunsanya jawe oye le Ọmọọba Ọlalekan Adeshina Basanya tawọn eeyan tun mọ si Old School gẹgẹ bi Ọtunba ilu naa.
Aafin ọba nla ni gbogbo eeyan ti ri bi wọn ṣe jawe joye le Basanya lori, ti wọn fun lọpa asẹ, ti wọn de e lade oye ti wọn si fun un niwe ẹri. Bamubamu ni gbogbo aafin alayeluwa kun, bẹẹ lawọn ẹsọ alaabo duro wamuwamu lati ri i pe wahala kankan ko ṣẹlẹ nibẹ lọjọ naa.
Lẹyin ti wọn jawe oye le baba oloye tuntun lori ti wọn fun un lọpa aṣẹ lariwo nla sọ ti gbogbo inu aafin si n ku ayọ ti wọn sọ pe ẹni to yẹ loye ni ọba gbe oye naa fun.
Lati ibikibi lawọn eeyan ti wa a ba baba oloye tuntun ṣayẹyẹ nla ọhun, pitimu si ni gbogbo oju agbo naa kun fawọn eeyan pataki lawujọ.
Awa naa ba baba oloye tuntun naa dupẹ lọwọ Ọlọrun, ewe a a mọri oo.

No comments:
Post a Comment