Bi ibo gomina ọdun 2023, ṣe n kan ilẹkun, eyi ti ibo gomina yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun yii. Oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, Agbẹjọro Olubiyi Ọtẹgbẹyẹ, ti rọ awọn ọmọọya ẹ, iyẹn Yewa-Awori, ti wọn wa ni Oke-Okun, fun atilẹyin nla lati le jawe olubori.
Ọkunrin naa sọrọ yii ninu iṣẹ to ran nibi ayẹyẹ ọdun kẹwaa ati aṣalẹ apejẹ tawọn olujolwo ọmọ ilu Ilaro, ti wọn wa ni United Kindom ati Ireland iyẹn Ilaro Descendant Union United Kingdom & Ireland, ṣagbatẹru ẹ. Eyi ti iyawo ẹ, Iyaafin Roli Ọtẹgbẹyẹ, jẹ lorukọ ẹ.
O rọ wọn lati jọ jumọ wa nirẹpọ ati iṣọkan, ki oun fi di gomina lọdun to n bọ, nitori pe agbajọwọ nikan lo le gbe ẹru de ori ati pe ọdun 2027, tawọn kan sọ pe kawọn tun duro de, ta ni o mọ nnkan to le ṣẹlẹ, o ni akoko awọn ree, ki wọn ma ṣe jẹ ko bọ mọ wọn lọwọ.
Bi atẹjade ọrọ to sọ naa ṣe lọọ ree, ‘Latigba ti ajọ eleto idibo INEC, ti gbe orukọ mi jade ni ọjọ kẹrin, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni oriṣiriṣi ti n ṣẹlẹ nilẹ Yewa-Awori, to fihan pe loootọ lawọn eeyan wa ti ṣetan lati rii pe ọkan ninu wa di gomina. Gbogbo awọn nnkan wọnyii ni mo ti papọ, to si jẹ ki igbagbọ mi duro digbi lati jade dupo labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC).
‘’ Ẹ ma jẹ ki n pirọrọ fun yin gbogbo nnkan lo ti n lọ letoleto koda awọn ti wọn n ro pe a o ti ṣetan ka duro de 2027,ibẹru lo si jẹ ki wọn maa sọ bẹẹ, amọ mo n da wọn lohun lawọn ibeeere ti wọn ko le dahun pe, kin ni idi ẹ ti ko fi jẹ 2023?, Ṣe awọn eeyan wa tun le foritii lati maa jiya fọdun mẹrin mii-in?, Ta lẹni to mọ ẹni ti yoo wa laye lọdun 2027? Njẹ awọn eeyan wa lati aarin gbungbun Ogun, yoo tun fọwọlẹran, ti wọn yoo tun faye ọhun silẹ ni 2027? Ṣe ko tun ni jẹ ibi ti ọpọ oludije yoo tun ti jade lati Ogun West lati wa dije ni 2027, Kin ni o le mu wa tiraka lọfun 2027, ti a ko ba le gba tikẹẹti ọhun ni 2023.
Oludije gomina ọhun tun sọ pe bi iṣejọba APC, ṣe n ṣe ilẹ Yewa-Awori, ninu ijọba ko jẹ nnkan to tẹ gbogbo araalu lọrun ati pe ipo ti wọn n fi wa si ko bojumu rara ninu ijọba wọn. O ni bi a ba ni ka bẹrẹ nipa eto ẹkọ, ipo ti wọn wa ko ṣe e fẹnu sọ bakan naa nipa ilera, itiju lo si n jẹ ti wọn ba de ọpọ ile iwosan, to jẹ pe awọn eeyan ko ri itọju to peye.
“ Pẹlu bawọn iya wa atawọn iyawo wa ṣe n ṣiṣẹ to, ṣe ni wọn n ko wọn si oko ẹru gbese, bẹẹ lawọn ọmọ wa lọkunrin ati lobinrin ni wọn fojoojumọ koju iṣoro airiṣẹ, ti ọjọ iwaju wọn gan-an ko ye wọn mọ pẹlu bi wọn ṣe kawe gboye lawọn ileewe giga. Awọn ajinigbe ti gbakoso gbogbo awọn abule wa, to jẹ ibẹrubojo lawọn eeyan ọhun fi n gbe, bẹẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ati afiniṣoogunowe naa ti gbode’’
Bẹẹ ni Ọtẹgbẹyẹ tun sọ pe ‘’ Awọn oju ọna wa ti bajẹ debi pe awọn araalu ko le gbe mọto wọn kọja, mo mu da yin loju pe bi mo ba le di gomina nipinlẹ Ogun, mi o ni dẹru wiwo le awọn araalu lori, nitori mo mọ iṣẹ wa ni lati gbe awọn eeyan dide, ki wọn kuro ninu iṣẹ, kawọn naa si le jẹ anfaani mudunmudun ijọba tiwa-n-tiwa’’
Oludije gomina ọhun wa rọ awọn Yewa-Awori, ti wọn wa ni Oke-Okun, lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọba alaye ati oun gẹgẹ bi oludije ti ko ni atako, ki wọn jọ wa niṣọkan, ki wọn jọ parapọ rii pe gbogbo ọmọ ilẹ Ilaro ati ọmọ bibi Yewa Awori, ati ipinlẹ Ogun, ni wọn forukọsilẹ ti wọn si ni kaadi idibo ti wọn yoo fi dibo foun gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ogunb, lọjọ kọkanla, oṣu kẹta, 2023.

No comments:
Post a Comment