Alaga egbe awon olokada lagbegbe Adura, to je okan gboogi ninu awon omoleyin alaga egbe Lagos state park management, Alaaji Musiliu Ayinde Akinsanya Mc Oluomo, iyen Alaaji Ismaila Otitoloju Esi Adura ti so pe ko si ohun to ku gbogbo omo Yoruba ku bayii lati gbarukuti oludije lipo aare legbe oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu fun aare orileede yii to fee se.
Esi Adura, lasiko to n ba Ojutole soro so pe ota Yoruba nikan ni yoo tako Asiwaju Tinubu lati di aare, nitori pe asiko Yoruba ree lati di aare.
Esi Adura ni gbogbo ona ni Tinubu fi kajue lati di aare, paapaa ipa nla ti agba oloselu naa ko fun ilosiwaju ati idagbasoke ipinle Eko, eyi to.tunmo si pe ti Asiwaju ba di aare, nnkan yoo senuure fun gbogbo wa lorileede yii.

No comments:
Post a Comment