IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 25 June 2022

Bi èèyàn márùn-ún ṣe pàdánù ẹ̀mi wọn nínú ìjàmbá mọ́tò ree


Taofik Afọlabi

ṣẹlẹ abuku nla waye lọjọ, Abamẹta, Satide to kọja yii, iyẹn  ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2022 nibi ti eeyan marun-un dagbere faye, tawọn mẹta mi-in si tun farapa ninu ijamba ọkọ kan to waye nikorita Day Waterman, loju ọna marosẹ Abẹokuta-Ṣagamu, nipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ ajọ to n sakoso igbokegbodo ọkọ ‘TRACE’ nipinlẹ Ogun, Babatunde Akinbiyi ṣe sọ, nnkan bíi aago mẹrin irọlẹ ku iṣẹju mẹẹẹdogun niṣẹlẹ aburu yii waye. Ninu ọrọ ẹ, o ni awakọ to wa ọkọ akẹru ti nọmba rẹ jẹ T-14214 LA lo n wa ọkọ niwakuwa, ti ijamba ọhun fi sẹlẹ.

Agbẹnusọ yii ṣalaye pe niṣe ni dẹrẹba yii yiwọ mọtọ pada lai bikita awọn ọkọ to wa nitosi ẹ, to si kọlu  ọkọ ayọkẹlẹ Mazda ti nọmba tiẹ jẹ KRD 975 HJ lasiko yi leeyan marun-un padanu ẹmi wọn, ti awọn mẹta sì farapa yannayanna.

Ohun to tilẹ waa buru ni pe niṣe ni dẹrẹba  ọkọ akẹru to ijama naa sa lọ gẹgẹ bí ọga Trace yii  ṣe ṣalaye.

 

A gbọ pe wọn ti gbe oku awon to ku  lọ silee igbokuusi ileewosan ijọba to wa niIjaye, l’Abẹokuta ati ti Idera to wa ni Ṣagamu.

Ajọ TRACE ba ẹbi awọn to padanu emi wọn kẹdun, bẹẹ ni wọn tun kilọ fawọn awakọ, paapaa awọn onitirela atọkọ akẹru, pe kí wọn maa tẹle ofin irinna, ki wọn yee ṣe bíi pe awọn nikan lọna wa fun.

No comments:

Post a Comment

Adbox