Ọsẹ to kọja yii ni agba-ọjẹ oṣere tiata Yoruba nni, Oloye AbdulGaniu Yinka Quadri tawọn eeyan tun mọ si Fagbamila ṣabẹwo si ọkan ninu awọn irawọ oṣere wa, Kẹmi Afọlabi ti ara rẹ ko ya.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, bi Kẹmi ṣe foju kan ọga ẹ ninu rẹ dun, ti gbogbo awọn ẹbi ẹ naa dupẹ lọwọ oloye ilu Oro yii pe o wa a ṣabẹwo si ọmọ ẹ lagbo awọn oṣere.
Lasiko to n sọrọ nipa iriri ẹ lasiko ti arun covid gbalẹ gidigidi, Yinka ni oun ranti igba ti oun bọ lati ilu UK wa si Naijiria, ti oun bẹrẹ si n ni awọn apẹẹrẹ eni to ba ni arun aṣekupani yii maa n ni ati pe ohun to jẹ ki ẹru ba oun ni pe bi wọn ṣe sọ pe arun naa ma yara pa ẹni to ba ni aisan ẹjẹ ruru eyi ti oun ni. O ni gbogbo asiko yii, awọn ẹbi oun, ara awọn ọrẹ ti wọn gba ruku ti oun titi ti ara oun fi ya, ti oun si bọ lọwọ aisan naa.
Ọṣere nla yii ni Ọlọrun to ko oun yọ lọwọ aisan yii yoo yọ Kẹmi naa lọwọ aisan to n ba a finra yii.
Bakan naa lo fi kun ọrọ ẹ pe ohun to ṣe pataki lasiko yii ni ki gbogbo awọn oṣere pata sugbaa Kẹmi, nitori pe ki i ṣe asiko ti a n ba n ṣe ayẹyẹ nikan lo yẹ ka ma a fifẹ han si ara wa. Asiko yii ni Kẹmi nilo wa daadaa, ko di digba ta a ba ku ka too mọyi ara wa.

No comments:
Post a Comment