IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 19 March 2022

Damendra di gomina awọn olorin fuji l’Ekoo



Ọjọ nla ti gbogbo awọn oṣere fuji ipinlẹ Eko ko le gbagbe bọrọ lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii, idi ni pe ọjọ naa ni wọn dibo yan awọn oloye tuntun ti yoo tukọ ẹgbẹ naa fun ọdun mẹta. Gbajumọ olorin fuji  to dide lati Ketu-Alapẹrẹ, iyẹn Mayor Tunde Adesina tawọn eeyan mọ si Damendra lo wọle gẹgẹ bii gomina ẹgbẹ naa tuntun. Idibo ọhun tawọn agba ẹgbẹ bii Alaaji Love Azeez L’Agerige, Alaaji Waheed Akangbe ati Baba Adawa Super wa a foju agba wo, bẹẹ ni aarẹ awọn onifuji lorileede yii, Alaaji Sikiru Ayinde Sensation  naa wa a bawọn mojuto, ti eto idibo naa si lọ pẹlu irọrun. Bakan naa naa ni gomina ẹgbẹ PMAN nipinlẹ Eko, Kabiyeesi Abdulkareem Olomide naa wa lori ijokoo lọjọ naa.

L ẹyin idibo ni wọn gba gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ nimọran lati wa ni isọkan ki wọn si sa gbogbo ipa wọn lati ri i pe ẹgbẹ awọn onifuji naa lọ soke si i. Ninu ọrọ ẹ, gomina tuntun dupẹ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn dibo yan pẹlu ileri pe oun ko ni i ja wọn kulẹ, bẹẹ lo dupẹ fun gbogbo awọn agba ẹgbẹ atawọn ti wọn ṣamojuto ibo naa.    

No comments:

Post a Comment

Adbox