Gbogbo awọn eeyan ti wọn ri agba oṣelu nni to tun jẹ oniroyin nla, Oloye Dele Mọmọdu loko ere ‘Alagbara’ ti gbajumọ oṣere tiata ati adari ere, Kẹhinde Adeyẹmi fẹẹ gbe jade ni wọn sọ pe fiimu ọhun yoo lagbara, bẹẹ loootọ ati lododo gbogbo ara ni ọkunrin oloṣelu naa fi ko ipa ti wọn fun un ninu ere naa.
Abbey Lanre lo dari fiimu naa, diẹ ninu awọn oṣere ti wọn kopa ninu ẹ ni: Yẹmi Ṣolade, Ọmọọba Jide Kosọko, Ogogo Taiwo, Mr. Macaroni, Tina Mba, Wolii Arole, Ngozi Nwosu, Moyọ Lawal atawọn mi-in
Gbogbo awọn eeyan ti wọn ti wo fiimu yii ni wọn sọ pe iṣẹ takuntakun ni gbogbo awọn elere ori itage wa to kopa ninu ẹ, bẹẹ ni wọn kan ṣaara si Kẹhinde Adeyẹmi fun agbekalẹ ọpọlọ to wa fiimu ọhun.

No comments:
Post a Comment