IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday, 10 March 2022

Temilola Akinwumi Dabira ninu fiimu 'Akanke Oba'


Itu meje ti ode n pa ninu Igbo ni okan ninu awon osere wa to sese n goke agba bo, Temilola Akinwumi pa ninu fiimu e tuntun ti oruko re n je Akanke Oba. Fiimu ohun to wa lori ikanni Yorubahood lori yutuubu lawn eeyan fi n gbadun are won bayii.


Fiimu 'Akanke Oba' ti agba-oje ati ogbontarigi osere, Alagba Rasak Olayiwola tawon eeyan mo si Ojopagogo dari e lawon osere to kopa ninu e ti lo gbogbo imo ati ogbon ti Olorun fun won.

Odun 2019 ni Temilola darapa mo awon osere, odo alaga egbe TAMPAN nipinle Oyo, Arabinrin Rose Odika lo ti kose ere ori itage yanju, lati igba naa ko ti boju weyin mo. Fiimu e akoko to se, ti yoo jade lojo Aiku, Sannde, ojo ketala osu yii lo pe ni '9th September'. Oga e, Rose Odika lo dari fiimu September 9th ohun.

 Omo bibi ipinle Osun ni Temilola, sugbon yunifasiti Eko to wa ni Akoka lo ti kawee jade


No comments:

Post a Comment

Adbox