IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 8 March 2022

Gbajumo olorin Islam, Sharafdeen Al-Bushrah yoo sayeye nla lEkoo



Ilu Eko yoo mi titi lojo Abameta, Satide, ojo kerinla osu karun-un, odun ti a wa yii, ojo naa ni gbajumo olorin Islam nni, Alhaji Sarafadeen Al-bushrah yoo sayeye onibeta.

Ayeye ohun ti yoo waye ni ile-igbafe 15:08 to wa ni Plot 2, Otunba Jobi Fele Way, Alausa, Ikeja ni kiko rekoodu tuntun jade, ami-eye ati idije alukuraani laarin awon omode.


Iya ojo naa ni Alhaja Tawakalitu Aweni Abiola Oladosu.

Awon ilu mo on ka olorin ti won yoo forin aladun da awon eeyan lara ya ni Ambassador Sulaimon Adio Atawewe, Agbaakin Abass Akande Obesere, Alhaja Rukayat Gawat, Alhaja Khadijat Omolara Omo America, Alhaja Aishat Ummu Niyass Olafimihan, Alhaja Modinat Ashabi Barrytide, Alhaja Maryam Akiki Oloriire ati Alhaja Tawakalitu Adunni Oloriire.

Eni ti yoo se waasi lojo naa ni: Sheik Issa Abubakar Authentic. 

Ankara lawon eeyan yoo fi wole sibi ayeye yii. Fun ankara tie, pe Al-bushrah sori nomba yii: 0803 634 218. 

No comments:

Post a Comment

Adbox