IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 21 March 2022

Ojo nla lọ́jọ́ Tí Kunle Babarinde kó Ìwé Yorùbá Ni Tòótọ́ Apá Kejì jade


Kìí ṣe àwọn èrò lásán ni wọ́n pẹ̀jú-pésẹ̀ sibi ìkójáde ìwé ìtàn Yoruba ti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníròyìn, Kunle Babarinde kọ, "Yoruba Ni Tooto (apá kejì) àti "Ìwé Òńkà Yorùbá", àwọn èèkàn-èèkàn ló gbárùkù tì í, lọ́jọ́ kẹtàdínlógún, oṣù yìí, nínú gbọ̀gàn NIJ, Ọgbà-Ikẹja.

Lẹ́yìn ètò yìí, ọ̀gbẹ́ni Babarinde, to tún jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan sárá fáwọn tí wọn kopa ribiribi níbi àṣeyẹ ọ̀hún.
Ó dúpẹ́ gidi lọ́wọ́ arakunrin Rotimi Akeredolu,  Gómìnà tí ìpínlẹ̀ Ondo, tí kọmíṣọ́nà àṣà àti ìṣe ṣojú fun, Otunba Wale Akinlọsotu ati Gómìnà Babajide Sanwoolu tí ìpínlẹ̀ Èkó tí akọ̀wé àgbà lẹ́ka ìròyìn àti ọgbọ́n àtinúdá Ọgbẹni Oluṣina Top ṣojú fún. 

Oloye ẹgbẹ́ Afenifere tó tún jẹ́ Gbonka Ààrẹ Ọ̀nà Kakaǹfò ilẹ Yoruba, Mogaji Gboyega Adejumọ ló ṣe ìdánilóẹ́kọ̀ọ́ lórí ìdí tí Yoruba ṣe gbọ́dọ̀ jí gìrì fún ìṣọ̀kan àti òmìnira.

Nínú àwọn àlejò kàǹkà ni ọ̀gbẹ́ni Gbenga Adefaye, tó jẹ́ olóòtú àgbà Vanguard newspaper, Ọtunba Adebọwale Atoloye aláṣẹ Mottel oil and gas, Alhaji Najeem Korodo alága ẹgbẹ́ NUPENG tẹ́lẹ̀ rí, Ààrẹ Látóòṣá ilẹ̀ Ibadan, Mọ́gàjí Hakeem Bakare, Aare Ọ̀nà Kakaǹfò tilẹ́ẹ Yorùbá, Iba Gani Adams tí Òsì Ààrẹ ṣójú fún, Alaaja Ṣẹrifat Adesọyin from lati SUBEB ìpínlẹ̀ Èkó, Alhaji Hakeem Ọlanrewaju Olaniran, aláṣẹ AMINYEMI Group of Companies, Alaaji Bashir Shorunke, aláṣẹ Bashy Group of companies.

Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Sam Ojo Omoloju-Jesu (Baba Authority) ló fakọyọ jùlọ, nígbà tó dẹ́rù bá gbogbo ènìyàn nibẹ pẹ̀lú owó ńlá tó ní òdo mẹ́fà!
Lọ́gán lórín sọ, àwọn alága patẹ́wọ́, tí àwọn adari eto sì bẹ̀rẹ̀ sí níí làágùn.

Lára àwọn àlejò ni baba Ori-Oke Ogo n'Ibadan, Àlùfáà Obafemi Akinade ti CAC Lion Of Judah, iranse Ọlọ́run obìnrin, Joy Ajanaku, ìránṣẹ́ Ọlọ́run obìnrin, Ogunlana àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

Àwọn akíkanjú sọrọsọrọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, Abiodun Adeoye Afefe Oro, ati arábìnrin Feyikemi Olayinka Mama Òwúrọ̀ lawà ni wọ́n darí ayẹyẹ náà.

Olorin ẹ̀mí, Bunmi Akinnaanu, Omije Oju Mi ló kọrin dá àwọn èèyàn lára yá lóòrè-kóòrè títí tí eto naa fii kẹ́sẹ-járí.

Àwọn èèyàn dunnú lóríi bí ọgbẹni Kunle Babarinde ṣe fara ṣíṣe lórí ìwé Yorùbá ni Tòótọ́, apá kejì àti akitiyan tó lọ́ọ̀rìn tó ṣe lóríi Ìwé Òǹkà Yorùbá, nínú èyí tó ṣe atupalẹ onka, dé orí miliọnu kan.

Gbogbo bí eto ṣe ń lọ ní wọn ń kéde pé àwọn ìwé yìí yóò wà káàkiri ilé ìtàwé lórílẹ̀ èdè yìí fún títa.

Credit: FIBAN EKO

No comments:

Post a Comment

Adbox