IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 20 March 2022

Ojo Furaidee to n bo yii layeye onibeta ti gbajumo olorin Islam Alhaja Monsurat Akobi-Esan yoo waye



Go̩ngo̩ yoo so̩ lo̩jo̩ ke̩e̩e̩do̩gbo̩n os̩u ti a wa yii, niluu Eko, o̩jo̩ naa ni o̩kan pataki ninu awo̩n olorin e̩sin islam, Alaaja Mo̩nsurat Ako̩bie̩san yoo s̩aye̩ye̩ onibe̩ta le̩e̩kan naa. Aye̩ye̩ o̩hun ni ifilo̩le̩ re̩ko̩o̩du e̩ tuntun to pe ni ‘Ojumo̩ Ire, ifilo̩le̩ ilees̩e̩ as̩araloge e̩ ati fifun awo̩n eeyan pataki kan lami-e̩ye̩.    Ge̩ge̩ bi Ako̩bie̩san s̩e so̩ fun wa, gbo̩ngan ‘KIO hall and event center’ to wa lojuo̩na  Clem ni  Adura laye̩ye̩ naa yoo ti waye. Lara awo̩n gbajumo̩ olorin islam ti wo̩n yoo forin dara lo̩jo̩ naa ni: Alaaja Misturah Amo̩ke̩ Aderounmu Ashafa, Alaaji Azeez Abio̩dun Saoti Are̩wa, Alaaja Maryam Akiki Oloriire, Alaaja Kifayat Singer atawo̩n mi-in.

Gbajugbaja so̩ro̩so̩ro̩ ori radio, Ambasando̩ Yo̩mi Mate̩ Ifakaleluyah ni yoo dari eto naa.

No comments:

Post a Comment

Adbox