Osan oni ni Ijoba Orilede Binni tu Ajijagbara Ominira fun Orilede Yoruba Sile, Oloye Sunday Igboho, ki o maa lole re laayo ati alaafia.
Won faa Oloye Sunday Igboho le Ojogbon Akintoye Akintoye tiise Aare egbe ijangbara ominira Yoruba ti a mo si Ilana Egbe omo Yoruba kaakiri Agbanlaye lowo. Adajo ni ejo ti won to ri re mu Sunday igboho ko lese nile, eto re lo nja fun, oun ri mumu naa gegebi ifi eto eni ponni loju ni ati fifi iya jeni. o wa pase ni kiakia tuu sunday sile ki o ma lo laayo ati alaaafia.
Bi e ko ba gbagbe, osu keje si ikejo odun to koja ni fi sunday si ahamo nigba ti o fe te oko leti lo si Ile Okere Germany oun ati Iyawo re Ropo tiise Omo bibi Ile Germany.
Ohun ti won so nipe Pasipotu ti o wa lowo re ti o fi fe tirafu kiise ojulowo ti ile Binni ati paapa ijoba ile Naijiria ti pase ki won mu nibikibi ti o ba ti fe gba salo sile okere. Esun ti Ijoba Naijiria fi kan an nipe o fe da ilu ru ati wipe, o fe fipa gba ijoba.

No comments:
Post a Comment