IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 1 January 2021

Gongo So Nibi Ayeye Onikobo Day-Gbogbo ilu lo dun yungbayungba

Titi aye lawon omo ilu Iboko Onikobo, nipinle Ogun  yoo maa ranti ojo kokandinlogbon, osu kejila, odun 2020. 

Ojo naa layeye ilu naa ti won pe ni Onikobo Day waye. Iwaju aafin oba ilu naa, Alayeluwa Oba Al-Maroof Iyanda layeye nla ohun ti waye.

Ojo yii ni kabiyeesi tun fi awon oloye je. Gbajumo olorin fuji nni, Alaaji  Sefiu Alao Adekunle tawon eeyan tun mo si Baba Oko lo dalu bole lojo naa. 

Gbajugbaja akewi, Alhaji Azeez Ajobiewe ati Ungly Boy naa dara lojo naa. Gbajumo sorosoro Alaroye Ibadan lo dari ayeye naa.

Bawon oba alaye se wa nine, bee lawon olowo, awon olola atawon otokulu naa peju-pese sibi ayeye Onikobo Day yii.

No comments:

Post a Comment

Adbox