Boya tabi sugbon ko si nibe, inu wahala nla ni okan ninu awon gbajumo osere tiata wa, Funmi Lawal, wa bayii, Koda oro obinrin naa ti wa nile-ejo majiireeti to wa ni Igbosere, niluu Eko.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin la gbọ pe Funmi Lawal f'ẹsun jibiti owo miliọnu meji naira kan Wolii Dele Ogundipe tawon eeyan mo si Genesis
Funmi ninu ẹsun naa lo ti sọ pe ilẹ kan ni Wolii Genesis fi lu oun ni jibiti, t'oun ko si ri owo naa gba pada, eyi to lo o m'oun pariwo sita.
A gbọ pe bi Funmi Lawal ṣe gbe ọrọ rẹ yii sita l'awọn eeyan ti pe akiyesi Wolii Genesis si i, ti wọn si lo o sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti Funmi fi kan oun, ati pe awọn ko jọ jokoo sọrọ ri, bee loun ko foju kan osere naa ri laye pun.
Bi ọrọ Funmi ṣe tan kaakiri lo mu ki Wolii Genesis f'ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti lati ba a ṣe iwadii kikun, ti wọn si lọ ọ gbe Funmi nibi to wa lati fọwọ wa a lẹnu
A gbo pe lasiko nbi ti wọn ti n fọrọ wa Funmi lẹnu wo ni teṣan ọlọpaa to wa ni Alagbọn n'ilu Eko, to si ri ibi ti ọrọ naa n lọ ni wọn lo jẹ ko jẹwọ fáwọn ọlọpaa pe irọ lasan loun pa mọ Wolii Genesis.
Alaye to se ni pe obinrin kan ti orukọ rẹ n je Bukky Jesse lo gbe owo fun oun lati ba Wolii Genesis lorukọ jẹ lati fi gba owo lọwọ ẹ.
Eyi lo mu k'awọn ọlọpaa f'ẹsun ibanilorukọjẹ kan Funmi, ti wọn si gbe e lọ s'ile-ẹjọ, bo tilẹ jẹ pe gbogbo ẹbẹ lati ma ṣe f'oju ba ile-ẹjọ lo ja si pabo.
Ohun ti a gbọ ni pe Loni-in ọjọ Aje, Mọnde, nigbejo yoo waye lori esun ibanilorukoje tawon olopaa fi kan Funmi Lawal.
No comments:
Post a Comment