IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday 4 January 2019

Oba Ara, Olorin emi, Atawon ebi e sinku baba won, Oloye Babajimi Joseph Onimole, lara oto


  
Bawon eeyan se n se poposin odun tuntun, niku wole were to mu baba gbajumo olorin emi nni, Efanjeliisi Rotimi Onimole Oba Ara, iyen Oloye Babajimi Joseph Onimole lo, leni odun mejidinlogorin, ti won si ti oku baba yii sile e to wa ni Alapere,Ketu, nipinle Eko. Ohun to je kayeefi nilu oro baba yii ni pe ojo ayeye ojoobi e, to ye ko pe eni odun mejidinlogorin gan-an lo wo kaa ile lo.  
Ojo Wesde to koja yii ni won se isin ale onigbagbo fun un, ijo ‘Christ Anglican Church’ to wa ni Alapere-Ketu ni won dari eto naa, leyin e lawon olorin dalu bole. Orisirii oro iwuri olowo iyebiye lawon eeyan so nipa baba yii, won lawon yoo padanu iwa rere ti Oloogbe naa ni.








































Ojo keji ni won seto isin ikeyin fun baba ninu ijo yii kan naa, leyin  e ni won gbe baba lo si ile ikeyin,ti ohun gbogbo di welo fun baba ajagun-feyinti yii.
Orin ati iweje-iwemu ni won fi pari eto naa lojo yii, nibi tawon olorin emi, awon sorosoro, awon osere tiata ti fi ijokoo ye Oba Ara atawon ebi e si. Gbajumo olorin emi yii nikan lomokunrin ti Baba Onimole bi. Awon omo atawon omo-omo ni won gbeyin baba naa.  
      

No comments:

Post a Comment

Adbox