IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday 17 September 2018

O TAN: WASIU AYINDE TI PADA LEYIN AMBODE, O LEYIN JIDE SANWOOLU TI TINUBU FA KALE LOUN WA BAYII

Latowo Taofik Afolabi

Ona to lagbara pupo ni wahala to n sele laarin asaaju egbe oselu APC lorile-ede yii, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ati gomina ipinle Eko, Ogbeni Akinwumi Ambode tun gba yo bayii. 

Idi ni pe gbajugbaja osere fuji to wa lara awon to se ipolongo fun Ambode lodun 2015, Alaaji Wasiu Ayinde ti gbogbo aye mo si Oluaye Fuji ti so pe eyin Jide Sanwoolu ti Asiwaju fa kale lati dije ibo abele gomina ninu egbe APC loun wa bayii.

Ninu oro Wasiu Ayinde, ti won tun n pe ni Arabanbi lo ti so pe gbogbo aye lo mo pe ti Buhari, Osinbajo ati ti Sanwoolu loun se ni gbogbo ojo. 

O ni gbogbo ohun ti Jagaban ba ti fe loun yoo ba fe. Orin to ko niyii, 'On your mandate, we shall stand, Bola, on your mandate, on your mandate, on your mandate, we shall stand'.
 

No comments:

Post a Comment

Adbox