IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 30 September 2018

IDI TEGBE OSELU APC EKO SE SUN IDIBO ABELE GOMINA DOJO MONDE REE

Ojo Abameta, Satide to koja yii lo ye kidibo abele sipo gomina ninu egbe oselu APC nipinle Eko ti waye, lojiji la gbo pe awon asaaju egbe naa ti sun un sojo Aiku, Sannde, ti gbogbo aye si n reti pe idibo naa yoo waye a fi bi kinni ohun se tun yi, ti won tun so pe ola ojo Aje, Monde ni yoo waye.

Ojutole gbo pe leyin ipade tawon asaaju egbe naa se niluu Abuja ni won ti fimo-sokan pe ki won sun idibo naa si ola
ojo Aje,Monde. Ohun tawon asaaju egbe yii so ni pe awon ko fe ki idaamu kankan sele lasiko idibo naa lo je kawon se gbogbo eto bi yoo se lo nirowo-irose.

Bakan naa la gbo pe ondije ipo gomina ninu egbe naa,Ogbeni Toyin Hamzat ti juwo sile fun ondije mi-in,iyen Babajide Sanwo-Olu. Pelu ohun ti Hamzat se yii, Sanwo-Olu ati Akinwumi Ambode to wa lori ipo gege bii gomina ipinle Eko ni won yoo koju ara won lola.         

No comments:

Post a Comment

Adbox