1n
jo,
Ninu ibanuje lawon oloselu ipinle Kwara, paapaa awon omo egbe oselu PDP wa bayii lori iku ojiji to pa okan lara won.
Eni odun merindinlogota (56) ni won pe Funke Adedoyin ti iku pa oju e de yii. Okan lara awon to sun mo on daadaa tie fidi e mule wi pe aisan jejere, iyen Cancer lo pa a.
Okan lara awon omo ile igbimo asoju-sofin ni Funke n se l'Abuja, bee omo gbajugbaja onisowo nla nni, Oloye Samuel Adedoyin nile Igbomina nipinle Kwara ni pelu.
Okan lara awon ogooro omo egbe oselu APC ti won ya lo sinu egbe oselu PDP nipinle Kwara laipe yii ni, bee lo ti figba kan je minisita ninu ijoba Olusegun Obasanjo.
No comments:
Post a Comment