IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday, 13 September 2018

GOMINA FAYOSE RANSE SI EFCC ' E MA A RETI MI LODO YIN LOJO KEEEDOGUN OSU TO N BO'

Bo tile je pe ohun tawon kan, paapaa awon ota e n so ni pe gbara to ba ti gbejoba sile losu to n bo ni yoo sa lo fawon ajo to n ri si sise owo ilu basubasu lorile-ede yii, EFCC. Awon kan tie so pe ona Kutonu ni yoo gba sa lo siluu oyinbo, sugbon okunrin naa ti ranse sajo yii pe ki won maa reti oun lofiisi won laago kan osan, ojo keeedogun, osu kewaa to n bo yii. Gomina ipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele Fayose la n so, o jare. 

Ninu leta ti okunrin naa tawon mi-in mo si Oshokomole ko si oga ajo EFCC lo ti so pe oun n bo waa salaye gbogbo esun ti won fi kan oun pe oun se owo ipinle Ekiti basubasu. O ni gege bii omo orile-ede yii tooto, oun jowo ara oun sile fun ajo yii, ki won beere oun ti won ba fee mo lowo oun nipa boun se sakoso ipinle Ekiti, nitori pe ko si ibi kankan toun sa lo ni toun, nigba toun ko jale.

Ohun ti yoo sele lojo yii lawon to n tele oro oselu lorile-ede yii, n duro de bayii.

     ,  

No comments:

Post a Comment

Adbox