IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 1 August 2018

Baba awon onifuji,Jenera Kolington Ayinla fee gbe rekoodu 'Yuppy Daddy' jade fodun Ileya

Bi odun Ileya se n sunmo etile, baba awon olorin fuji lorile-ede yii, Alaaji Kolawole Ayinla Ilori, ti gbogbo aye mo si Jenera Kolligton Ayinla, ti pari ise lori rekoodu e tuntun to pe ni 'Yuppy Daddy'.

Ninu atejade ti agbenuso agba oje olorin naa, Taofik Afolabi,  fi sowo si wa lo ti so pe asiko odun Ileya to n bo yii ni rekoodu naa yoo gori igba fun igbadun awon eeyan. O ni opolopo alujo ati orin gidi ni Kebe-n-Kwara ko jo sinu rekoodu tuntun yii.

Bakan naa lo fi to wa leti pe ojo Abameta, Satide to koja yii ni Oba ilu Orile Agbado, Oba Taiwo Orija jawe oye le Kolligton lori gege bii Akinrogun ilu naa, leyin e ni baba omo bibi ilu Ilota,nipinle Kwara naa forin aladun da awon eeyan laraya,ti gbogbo adugbo naa dun yugbayugba,



No comments:

Post a Comment

Adbox