IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 1 May 2026

Àgbà ọ̀jẹ̀ olórin fújì fẹ́ẹ́ ṣayẹyẹ ńlá l’Ékòó



Ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹfa, ọdun yii ni agba-ọjẹ olorin fuji nni, Alaaji Azeez Ayinla Tutuye yoo ṣayẹyẹ nla niluu Eko. Ayẹyẹ ọhun ni ikojade rẹkọọdu ẹ tuntun to pe ni ‘Determination’ ati ayẹyẹ ọjọọbi ẹ. Ilu Mushin layẹyẹ ọhun yoo ti waye.

Ilu mọ ọn ka oṣere fuji, to tun gbajumọ daadaa, Aarẹ Shina Akanni ni yoo ṣaaju awọn olorin bii Askari to n kọ fuji, Alaaja Agba Musiliyu Arikẹ, Alaaji Musbau Alani ni yoo ṣaaju awọn ti yoo kọrin nibi ayẹyẹ naa.

 Lasiko to n sọrọ nipa ayẹyẹ naa, Tutuye sọ pe oun lo asiko yii lati pe gbogbo awọn ololufẹ oun pe ki wọn waa fi ọjọ naa yẹ oun si. Bakan naa lo fi kun ọrọ ẹ pe  aabo to peye yoo wa fun gbogbo awọn eeyan nibi ayẹyẹ naa.

No comments:

Post a Comment

Adbox