IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 8 April 2026

Ọ̀la leto ìsinku Ẹ̀rẹ̀kẹ́nisọ́ọ̀bù, gbajúmọ̀ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ to ku yoo bẹrẹ


 Gbogbo eto lo ti pari lori aṣekagba ayẹyẹ oku gbajumọ sọrọrsọrọ ati agba ọjẹ elere ori itage nni, Oloye Timothy Fẹmi Agboọla tawọn eeyan mọ si Ẹrẹkẹnisọọbu. Gẹgẹ bi awọn eleto ayẹyẹ naa ṣe fi to wa leti, Ọjọbọ, Tọsidee iyẹn ọjọ kẹsan-an oṣu kẹrin ti a wa yii ni eto alẹ awọn oṣere yoo waye nile igbafẹ Lyta Hotel to wa ni Gowon Estate, ni Ẹgbẹda niluu Eko. Lati aago meje alẹ di ọjọ keji leto naa yoo fi waye. Ọjọ Ẹti, Furaidee ọjọ kẹwaa, leto isinku yoo waye ni gbọngan ‘Class Hall’ to wa ni oju ọna LASU si Igando ladojukọ ile-ẹpo Petrocam. Lati aago mejila ọsan leto naa yoo bẹrẹ.   

Gbogbo eeyan, paapaa awọn oṣere pẹlu awọn sọrọsọrọ ni wọn reti nibi eto isinku naa.

No comments:

Post a Comment

Adbox