IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 3 April 2023

Gọngọ sọ nìbi wáàsí ààwẹ̀ Ramadan ijọ ‘Istijabah Du'ah’


Ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii ni ijọ alasalatu ti orukọ rẹ n jẹ ‘Istijabah Du'ah’ ṣe waasi oṣu aawẹ Ramadan ọdun yii. Lati ibi gbogbo lawọn eeyan ti waa ba ijọ naa ti Ọlọrun tọwọ  Sheikh Abdul Ganiy Akewusọla  Ajibade da silẹ jokoo waasi aawẹ ọhun.Olu ijọ Asalatu naa to  wa niluu Idiroko, nipinlẹ Ogun waasi naa ti waye.  Yatọ si waasi aawẹ yii, ọjọ naa ni wọn tun ko iwe adura ijọ naa jade, ti wọn si tun si mọsalaasi tuntun.

Sheikh Abdullateef Ademola Ademoye  lo se waasi lọjọ naa pelu akole yii 'Ojuse iya si ọmọ  ti ọmọ le fi ni alubarika

Lara awon eeyan pataki lawujo ti wọn wa nibẹ lọjọ naa ni:Alaaji Rasak Adeleke Agbawo, Alaaji Gidado,Onipokia Ọba Olusọla,Oniko ti idiroko, Oloye Titus Oppressor, Alaaji Saheed Babatunde Oluọmọ Kutonu atawọn mi-in.

Alaaji Sulaimọn Oyeniran to je olugbalejo lọjọ naa dupẹ lọwọ awọn eeyan  to fi ọjọ naa yẹ wọn si, bẹẹ lo gbe osuba o kare fun Sheik Akewuṣọla to jẹ oludasilẹ ijọ Istijabah.

 


No comments:

Post a Comment

Adbox