IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday, 14 April 2022

Ilera ọfẹ jẹ mi logun ti mo ba di gomina lọdun 2023- Dokita Samuel Adeyẹmi


Dokita Samuel Olufẹmi Adeyẹmi, Oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oṣelu Action Alliance, nipinlẹ Ogun, ti sọ pe ọkan pataki to jẹ oun logun ju toun ba wọle fun ipo naa ni lati rii pe iwosan di ọfẹ ati lati sọ ipinlẹ naa di ibi irinajo igbafẹ feto ilera.

 Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin sọrọ nipa erongba ẹ lati di gomina ninu ibo to n bọ lọdun 2023. O sọ pe eto ilera ko ṣẹṣẹ bẹrẹ nipinlẹ ọhun ati pe nigba ti Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Oloye Ọlabisi Ọnabanjọ, fi wa nipo ni wọn ti kọkọ bẹrẹ ti wọn si ṣe aṣeyọri.

O sọ pe oun yoo rii pe awọn ọmọde titi di ọmọ ọdun mejidinlogun, ni wọn kọkọ jẹ anfaani yii ati pe bo ba ṣe n tẹ siwaju lawọn yoo ṣe de ọdọ awọn agbalagba.

Dokita Adeyẹmi to tun jẹ oniṣiro owo ati agbẹjọro tun fi kun ọrọ ẹ pe awọn iriri toun ti ri lawọn iṣẹ toun yan an laayo loun yoo lo lati ri pe irọrun deba awọn araalu.

Bẹẹ lo tun sọ pe awọn yoo tun rii pe iṣẹ ati iya dopin fawọn eeyan paapaa awọn arugbo, nitori awọn yoo ṣeto kan nibi ti wọn yoo ti gba tikẹẹti ti wọn yoo fi maa fun wọn lounjẹ loṣooṣu.

Bakan ni oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu AA, tun sọ pe itiju nla lo jẹ nilẹ Yoruba, pe titi di akoko yii, Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ, ni wọn maa fi n ṣe odiwọn, pe wọn ko tii ri eyi to tayọ.

Idi niyii to fi ni oun pinnu lati ṣe awọn nnkan to tayọ nipa agba oṣelu naa, nipa ifarajin ati ifẹ ọmọniyan bẹẹ ki oun gbogbo ko si maa lọ, bo ṣe yẹ ko lọ.

Ọkunrin waa sọ pe ẹgbẹ AA, ipinlẹ Ogun ti wa gbaradi bayii lati gbajọba mọ Dapọ Abiọdun lọwọ lọdun 2023, nitori ojoojumọ lawọn araalu n pariwo pe ijọba APC, ti sun wọn.

Ati pe kaka ki wọn tun ilu ṣe,ṣe ni wọn tun bajẹ si, oun si mọ pe ibo to n bọ yii ni wọn yoo fi le wọn kuro niluu, ti AA yoo si gbajọba, O waa ki awọn araalu ku irọju.

Bakan naa lo tun gbawọn lamọran lati rii pe wọn gba kaadi idibo wọn, nitori eyi ni yoo jẹ ki wọn ni anfaani lati gba ijọba to wa lode yii sita pẹlu igbalẹ wọn.

1 comment:

  1. All things are possible at the God's appointed time

    ReplyDelete

Adbox