IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 12 September 2026

Awọn ara agbegbe Ifọ keji ko nii kabamọ pe wọn dibo fun mi lọdun 2027- Ọnarebu Sadiq Azeez Babatunde



Ọnarebu Sadiq Azeez Babatunde, oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, ti fọkan awọn eeyan ẹ balẹ ni agbegbe ẹkun Ifọ keji pe didun ni ọsan yoo so bi wọn ba le dibo foun ninu ibo ọdun 2027.

O sọrọ yii lakooko to bawọn oniroyin sọrọ, o sọ pe oun fẹẹ lọ sin awọn eeyan oun,ki wọn ba le jẹ anfaani mudunmudun ijọba tiwa-n-tiwa.

O ṣọ pe kii ṣe ọrọ ẹnu Ifọ keji jẹ oju taye tawọn araalu to wa nibẹ ko yẹ ki wọn foju bintin wo, bẹẹ lo si jẹ ibugbe ti okoowo pọ si, ti owo ti n wọle si apo ijọba ipinlẹ ati apapọ.

Sadid tun ṣalaye siwaju pe ipo toun dije fun yii bi aṣofin, oun gbọdọ rii pe o mu nnkan rere wa fawọn to n gbe nibẹ paapaa imayedẹrun ni eyi ti yoo mu irọrun  wa.

O ni," Bi awọn eeyan mi ni agbegbe Ifọ Keji ba le dibo fun mi gẹgẹ bi aṣofin wọn labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, mo maa rii pe ajọṣepọ to danmọran wa laarin emi atawọn araalu lati le maa mọ bi nnkan ṣe n lọ, mi o si ni jẹ aye alafo ibaṣepọ ṣi ṣilẹ laarin wa"

O fikun ọrọ ẹ pe ipo toun dije fun yii ki i ṣe nipa imọtara ẹni rara bi ko ṣe lati fi sin araalu tọkantọkan ki wọn si le jẹ anfaani mudunmudun ijọba tiwa-n-tiwa.

Babatunde tun ṣalaye lara awọn nnkan to nii lọkan, o sọ pe" Bi mo ṣe woye, ironilagbara ṣe pataki fawọn araalu, nitori bi ọrọ aje wa, nitori eyi mo pinnu lati gbe awọn okoowo diẹdiẹ dide nibi ti wọn yoo ti maa rọwọ mu ṣẹnu paapaa awọn ọlọja, ọdọ atawọn oniṣẹ ọwọ mii, ki i ṣe lati fun wọn ni ẹja, bi ko ṣe bawọn naa yoo ṣe ma pa ẹja".

O tun ṣọ pe ilera ṣe pataki fawọn agbegbe ti aṣofin ba m ṣoju, oun to si buru ni pe ki alaboyun tabi ọmọde ku iku aitọjọ, idi si ree to fi jẹ pe oun yoo rii pe atunṣe deba awon ile iwosan ti wọn ti n gba itọju ni Ifọ keji paapaa lawọn bii Akute, Alagbado, Alagboole, Ijoko atawọn ibo mii.Ti wọn yoo si tun pese awọn ohun elo to ba yẹ fun wọn.

Babatunde tun sọ pe," Gbogbo wa la mọ
 pe pataki ni ẹkọ jẹ, taa si mọ pe awọn ọmọ wa ni ọjọ ọla wa,erongba mi ni lati mu atunṣe bawọn ileewe alakọọbẹrẹ ati girama ijọba, bẹẹ ni mo tun maa ṣe iranwọ fawọn to ba fẹẹ ṣe idanwo GCE/UTME,eyi yoo mu adinku bawọn ti wọn ko le pari ẹkọ wọn.

O sọ pe idagbasoke ko le ba ilu tawọn ọna ko ba dara tabi dun un wo, idi niyii toun yoo fi ri pe oun gbe awọn abadofin kan dide lati rii pe ijọba ran wọn lọwọ lati ṣatunṣe ki wọn si pese  ina sola nitori aabo oju popo.

Oludije ADC tun wa ṣeleri pe bi wọn ba dibo yan oun wọle ninu ibo to n bọ yii, loorekoore ni wọn yoo ma ri oun lati maa fi abọ jẹ wọn nipa bi nnkan ba ṣe n lọ.

O wa sọ pe ikuna ni yoo jẹ foun bawọn to n ṣoju fun ko ba ri ounjẹ jẹ, ti wọn ko rowo ọmọleewe san, ti eto aabo wọn mẹhẹ, ti wọn ko ni ilera to peye, nitori ẹ loun ṣe n lọ gẹgẹ bi agbẹnusọ wọn, toun fẹẹ lọ sin wọn, oun wa bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ wọn, ki wọn fi ibo gbe oun wọle.

No comments:

Post a Comment

Adbox